Ẹ̀ bàá wádìí ní gbogbo ayé yìí, ẹ ò lè mọ ohun tó wà láàrin èmi àti Seyi Makinde – Olopoeyan

Ẹ̀ bàá wádìí ní gbogbo ayé yìí, ẹ ò lè mọ ohun tó wà láàrin èmi àti Seyi Makinde – Olopoeyan

Adari pataki ninu awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP) ni ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Abulrasheed Adebisi Olopoeyan, ti papa ba BBC Yoruba lati fesi nipa nnkan to wa laarin oun ati Gomina Seyi Makinde to fi n fa ariwo lori ayelujara.

Abdulrasheed ti ọpọlọpọ maa n pe ni Olopoeyan sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pe:

“Ohun to wa laarin emi ati gomina Seyi Makinde, ko sẹni to lee mọ ju pe ija ti pari lọ, ẹ o maa ri wa papọ bayii”.

Olopoeyan ṣalaye pe oun ati Seyi Makinde ti jọ wa tipẹ, ko si ki n ṣe ẹni ti oun ko mọ tẹlẹ torinaa ki awọn eeyan ma rii bi nnkan babara.

Bisi Olopoero

“Abi Olopoero ti fẹ lọ darapọ mọ PDP ni Oyo ni?”

Bakan naa ni olopoero sọ fun BBC Yoruba pe ọpọlọpọ iroyin loun ti n gbọ nita.

To fi mọ pe o sọ pe awọn kan ti n pe oun lori foonu lati beere pe ki lo ṣẹlẹ.

“Ẹnikan tun bi mi laarọ yii wipe ṣe mo fẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni mo si ni mi o wa o, ki awọn PDP ma lọ ro pe mo fẹ wa gba nkan lọwọ wọn ni”.

Gbajugbaja oloṣelu naa to wa ni ipinlẹ Oyo sọ pe wọn le maa ri awọn papọ lode torinaa, ki ẹnikẹni ma ro o, “ọrọ laarin emi ati Seyi Makinde ni kii ṣe ọrọ ara ita”.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí