Ẹ bá wa bẹ Pásítọ̀ Àgbàlá Gabriel kó má gba ilé tó ń kọ́ fún Iya Ibeji Omo Arayele – Ronke Oshodi Oke

Ronke, Pasitọ, Iya Ibeji ati Foluke

Oríṣun àwòrán, Collage

Gbajumọ osere tiata, Ronke Osodi Oke ti da si ọrọ awuyewuye to n lọ lọwọ lori ile ti Pasitọ kan nilu Ibadan n kọ fun agba ọjẹ osere tiata, Iya Ibeji Omo Arayele to n saisan.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awuyewuye n waye lori ayelujara laarin Foluke Daramola, awọn ololufẹ Iya Ibeji Omo arayele ati Pasitọ Agbala Gabriel.

Foluke lo n salaye pe inu igbo ni Pasitọ naa kọle si fun agba osere tiata naa, eyi to le tete seku pa a, ti awọn ọrẹ oun si ti gba ile fun si Ikorodu nipinlẹ Eko.

Amọ awọn ololufẹ agba osere naa ti tutọ soke foju gbaa, ti wọn si n foju abuku wo Foluke lori ero rẹ naa.

Amọ ni bayii, agba osere tiata miran, Ronke Ojo, ti ọpọ eeyan mọ si Ronke Oshodi Oke ti rawọ ẹbẹ si pasitọ ijọ Agbala Gabriel lori awuyewuye to n waye pẹlu ọrọ ilẹ ati ile to kọ fun Iya ibeji ọmọ araye le.

Ronkẹ Osodi Oke ranṣẹ ẹbẹ si pasitọ naa ninu fidio kan to fi si ori ayelujara.

Gbajugbaja oserebirin naa ṣalaye pe lorukọ ẹgbẹ oṣere TAMPAN ni oun n parọwa ẹbẹ naa.

Bakan naa lo tun pẹtu si gbajumọ osere akẹgbẹ rẹ Folukẹ Daramola pe ko fọwọ wọnu lori ọrọ naa.

Ko si ilẹ nigboro mọ, abule ni ilẹ ku si lati kọ ile si, ibi alaafia ni ibẹ – Ronke Oshodi Oke

Ronke wa n fidi rẹ mulẹ pe ko sibi ti eeyan ti fẹ ri ilẹ ra mọ laarin igboro, inu igbo nikan ni ilẹ ku si lati kle si.

O ni Pasitọ Gabriel kọ ile fun iya ibeji lati tun ọjọ alẹ agba osere tiata naa se ni.

O wa n rọ awọn eeyan lati bẹ Pasitọ naa, ki wn maa baa gba ilẹ naa mọ iya ibeji lọwọ.

“Abule ni ibi ti wọn kọ ile si, ibi alaafia ni ibẹ, ti iya ibeji si maa pada joko sibẹ.

Inu wọn maa pada dun, ti wọn yoo si mọ pe awọn wa sile aye asan, mo si n bẹ alagba Gabriel lati mase gba ile naa lọwọ iya ibeji.”

Oshodi Oke tun wa rawọ ẹbẹ si Foluke Daramola ati Alagba Gabriel lati mase binu si ọmọ iya ibeji ọmọ araye le to n jẹ Ronke.

O ni ọmọ kekere lo n se Ronke naa, ohun to si se, oun gan le hu iru iwa bẹẹ.

O wa rawọ ẹbẹ si igun to n binu pe ki wọn fi ọwọ wọnu, ki wọn si jeburẹ.

Bakan naa lo ni ki awọn eeyan mase binu si Foluke nitori alaafia iya ibeji nitori oun lo ti n tọju iya ibeji bọ.

Bawo lọrọ ṣe bẹrẹ laarin Pasitọ ijọ agbala Gabriel, Folukẹ Daramola ati iya ibeji ọmọ araye le?

Pasitọ Agbala Gabriel, iya ibeji ọmọ araye le ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel global/Facebook.com

Bi ẹ ko ba gbagbe, awuyewuye waye lori ile ti Pasitọ ijọ Agbala Gabriel n kọ fun iya ibeji ọmọ araye le lẹyin ti awọn ọmọ oṣere naa gbe e tọrọ iranwọ lọ si ṣọọṣi rẹ nilu Ibadan.

Amoṣa ọrọ naa ko dun mọ Folukẹ Daramola ninu nitori ninu iwoye rẹ iru ile bẹẹ kọ ni iya ibeji ọmọ araye le nilo nitori ilera rẹ.

Folukẹ Daramola ni ibi ti ile naa wa jinna ju fun gbajumọ osere naa leyi to ni yoo tubo pa kun wahal ilera rẹ ni nitori ìwọnba perete lawọn eeyan ti yoo lee maa wa a de ibẹ.

O wa tun ṣalaye siwaju sii ninu fidio kan to ṣe pẹlu lori ayelujara pe oun at’awọn eeyan kan ti gba ile fun gbajumọ osere naa nilu Ikorodu nibi ti yoo maa rọrun fun dokita to n tọju rẹ lati de.

Folukẹ Daramola

Oríṣun àwòrán, Foluke Daramola fans page/ Facebook.com

ọrọ yii ko sebi ẹni dun mọ Pasitọ agbala Ga riel at’awọn ololufẹ rẹ ninu pẹlu bi wọn ṣe fi oju iwa fifi oju oloore gungi wo ọrọ naa .

Pasitọ naa pẹlu sọrọ ninu fidio kan lori ayelujara pe ohun yoo.tẹsiwanu lati pari ile naa ati wi pe nnkan to ba wu iya ibeji ọmọ araye le ko fi ile naa ṣe ti oun ba ti pari rẹ.

Amoṣa o, Ronkẹ Osodi oke, ninu fidio to ṣẹṣẹ gbe sita loei ayelujara dupẹ lọwọ awọn mejeeji, o ni ere ko le dara fun iya ibeji omo arayele lawọn mejeeji nsa nitori naa ede ni ko ye ara wọn.

O ni ko ni tọna ki awọn mejeeji fi gbajumọ osere naa silẹ ko ku nítorí ipe ti olukuluku gba lori rẹ yatọ si ara wọn ko si yẹ ko di ara wọn lọwọ.

Gbajumọ oṣere naa ni kii ṣe pe awọn agbaagba osere ko gbọ si iṣẹlẹ naa ṣugbọn wahala gbọyisọyi ti awọn eeyan maa n ṣe lori ayelujara lo n ba ọpọ wọn lẹru.

O wa rawọ ẹbẹ si Pasitọ naa lati mase gba ile naa pada lọwọ eekan agba oserebirin naa, ki o si mase ro awọn aisedede ọmọ oserebirin naa lori ọrọ ọhun.