Buhari, dáríjin Igboho àti Kanu láti fòpin sí ìjìjàgbara ní Naijiria – Bíṣọ́ọ́bù ìjọ Eleétò

Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho

Biṣọọbu agba kan ninu ijọ Eleto, Samuel Chukwuemeka Kanu-Uche ti gba Aarẹ Muhammadu Buhari ni imọran lati forijin adari ẹgbẹ awọn IPOB, Nnamdi Kanu ati ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho.

Alufaa naa ni ṣiṣe eyii yoo fopin si erongba awọn eeyan naa lati jẹ ki ẹya wọn yapa kuro lara Naijiria.

Kanu-Uche lo sọ ọrọ naa lasiko ijiroro pẹlu awọn akọroyin niluu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

  • Igboho ń jà fún ìran rẹ̀ ni, kìí ṣe apànìyàn, ìjọba Benin, ẹ bá wa tú u sílẹ̀
  • Buhari kíyèsára, gbèsè Naijiria pọ̀ ju owó tó ń pa wọlé lọ – AfDB
  • Àṣìṣe márùn ún tí àwọn lọ́kọláyà ńṣe nípa owó
  • Kíndìnrín àti ẹ̀dọ̀fóró Sunday Igboho ni àìsàn ń ṣe – Yomi Aliyu
  • Agbébọn yabo Catholic Seminary ní Kaduna, wọ́n jí èèyàn mẹ́ta, ọ̀pọ̀ farapa
  • “Buhari, oúnjẹ ní ko wá síkùn aráàlú ná, má fi N13.3bn gbé ọlọ́pàá agbègbè kalẹ̀”
  • Chidinma yọjú sílé ẹjọ́ lónìí lórí ẹ̀sùn pípa Usifo Ataga àmọ́ ohun tó wáyé rèé
  • “Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí”
  • Obìnrin mẹ́fà àti ọmọ wẹ́wẹ́ mẹsan sá ní àhámọ́ Boko Haram lẹ́yìn oṣù mẹ́fà

Gẹgẹ bii nnkan to sọ, ọpọ eeyan ni Naijiria lo jẹ ọmọlẹyin awọn ajijagbara ọhun, o si yẹ ki ijọba apapọ lo awọn ọmọlẹyin wọn lati wọle si awọn ajijagbara naa lara.

O tun dabaa pe ki ijọba máa san ẹgbẹrun marundinlọgbọn fun awọn ọmọ ikọ Boko Haram to ba ronupiwada nitori iṣẹ ati iya lo n mu ki ọpọ eeyan kan darapọ mọ wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nigba to n sọrọ lori Sheikh Ahmad Abubakar Gumi, o ni o yẹ ki ijọba le lo ẹlẹsin Musulumi naa lati fopin si gbogbo iwa janduku lapa oke ọya nitori ipa ti ọkunrin ọhun ni lori awọn janduku naa.

Kanu-Uche sọ pe “Awọn wo lo lọ n gbe owo itusilẹ lọ fun awọn janduku? Kaka ki ijọba maa bu ẹnu atẹ lu Gumi, ni ṣe lo yẹ ki wọn wa ọna lati ba a ṣiṣẹ pọ lọna ati fopin si iwa janduku.”

“To ba jẹ pe lootọ ni Gumi maa n lọ sinu igbo lati lọ ba awọn janduku sọrọ ti awọn janduku naa si maa n gbọ tirẹ, ijọba le ba wọn sọrọ lati ipasẹ rẹ.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ẹ jẹ ki n sọ fun ni gbangba bayii pe awọn oloṣelu lo n lo awọn ọdọ wọnyii fun iwa janduku, ti ijọba ba n fun wọn ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn loṣooṣu, wọn ko ni máa ji eeyan gbe mọ, ounjẹ ni wọn n wa, ko si nnkan mii.”

Biṣọọbu ọhun sọ siwaju si pe ijọba gbọdọ pe Kanu ati Igboho fun ijiroro.

O ni “O yẹ ki ijọba naa tun pe Nanamdi Kanu ati Sunday Adeyemo si ipade lori bii wọn yoo ṣe yanju gbogbo rogbodiyan to wa nilẹ yii.

Alufaa ọhun pari ọrọ rẹ pe “Ẹ ma pe awọn ni agbesumnọmi, ti ẹ ba pe wọn ni agbesumọmi yoo di wahala.”

“Ṣugbọn ẹ pe wọn ni ọmọ, ki ẹ si sọ fun wọn pe, ẹyin ọmọ wa, ẹ wa o, ẹ jẹ ki a ni ifikunlukun…. yoo ṣiṣẹ bii idan.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ