Benjamin Mendy sọ pé 10,000 obìnrin ni òun ti bá lòpọ̀ – Ẹlẹ́rìí sọ nílé ẹjọ́

Benjamin Mendy

Oríṣun àwòrán, Reuters

Agbabọọlu Manchester City, Benjamin Mendy ti n koju igbẹjọ lori ẹsun ifipabanilopọ, lara eyi to ti sọ fun ẹnikan lara awọn obinrin meji ọhun pe ‘ko si nnkan to buru nibẹ, nitori pe ẹgbẹrun mẹwaa obinrin ni oun ti ba lopọ’.

Wọn fi ẹsun kan ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa pe o kọlu obinrin naa, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun nigba naa nile rẹ to wa ni Mottram St Andrew, Chesire, ni oṣu Kẹwaa ọdun 2020.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan an pe o fi ipa ba obinrin mii, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn nigba naa lo pọ, nile rẹ lọdun meji ṣaaju.

Agbabọọlu naa ni oun ko jẹbi ẹsun mejeeji.

Ile ẹjọ Chester Crown ni wọn ti gbọ ẹsun rẹ.

Ṣaaju ni adajọ to kọkọ gbọ awọn ẹsun naa, Stephen Everett, sọ fun igbimọ awọn eeyan mejila to n gbọ ẹsun naa bayii pe ile ẹjọ rii pe agbabọọlu naa ko jẹbi awọn ẹsun ifipabanilopọ ti awọn obinrin miran fi kan an ninu igbẹjọ kan to pari loṣu Kini, ọdun yii.

Onidajọ Everett sọ pe igbimọ olugbẹjọ to kọkọ gbọ ẹjọ naa ko ri idajọ ṣe lori awọn ẹsun meji ti igbimọ tuntun yii n gbọ, idi si ree ti wọn fi tun ẹjọ naa bẹrẹ.

Adajọ naa kilọ fun awọn ọmọ igbimọ tuntun lati gbe idajọ wọn kalẹ lori awọn ẹri ti wọn ba gbe wa siwaju wọn, kii ṣe lori awọn ẹri ti ile ẹjọ akọkọ gbà.

Agbẹjọro to n rojọ tako Benjamin, Benjamin Aina KC ni ibẹrẹ igbẹjọ pe Benjamin Mendy saba ma n ṣe àpèjẹ ninu ile rẹ, to si ma n pe tọkunrin-tobinrin, ṣugbọn igba meji lo ti hu iwa ti ko tọ si meji lara awọn alejo rẹ obinrin.

Ọgbẹni Aina sọ pe Mendy pade obinrin akọkọ to jẹ akẹkọọ ni UK, ni ile igbafẹ kan niluu Barceloba lọdun 2017, ti obinrin naa si pada sunmọ ẹnikan lara awọn ọ̀rẹ́ Benjamin.

Lẹyin ọdun kan lo lọ ṣe abẹwo si ọrẹ Mendy nile agbabọọlu naa.

Ile ẹjọ gbọ pe ni ọjọ keji, nibi ti obinrin naa ti n wẹ̀ ni Mendy ti wa ba lai wọ aṣọ kankan yatọ si sokoto penpe, pẹlu nnkan ọmọkunrin rẹ to ti dide ninu ṣokoto.

Wọn fi ẹsun kan agbabọọlu naa pe o fa obinrin ọhun mọra, to si gbiyanju lati ba a lopọ lori ibusun, ṣugbọn ti obinrin naa kọ̀ jalẹ.

Lẹyin ọdun meji si asiko naa, obinrin keji ni tiẹ ṣere lọ si ile ọti kan pẹlu awọn ọrẹ rẹ ni Alderley Edge niluu Chesire, nibi ti ko jina si ile Mendy. Mendy gba a ni alejo nile rẹ.

Obinrin yii fi ẹsun kan agbabọọlu naa pe o gba foonu lọwọ oun, to si salọ si ọna yaara ibusun rẹ nigba ti oun n gbiyanju lati gba foonu oun pada lọwọ rẹ.

Ọgbẹni Aina sọ pe Mendy sọ fun obinrin naa pe “wo, mo kan fẹ yẹ ọ wo ni”, o si sọ fun pe ko bọ aṣọ.

“Obinrin naa bọ aṣọ rẹ ku awọtẹlẹ nikan, Laisko naa ni Mendy ju foonu rẹ si ori ibusun.

“Nibi ti obinrin naa ti sare lọ mu foonu naa, ni agbabọọlu ọhun ti dimọ ọ lati ẹyin, to si fi ipa ba a lopọ botilẹ jẹ pe obinrin naa sọ pe oun ko fẹ ẹ ni ibalopọ.”

Ọgbẹni Aina sọ pe Mendy wo obinrin naa loju, o si sọ fun pe ‘o ti n tiju ju. Lẹyin naa lo tun sọ pe “ko si nnkan to buru ninu nnkan ti a ṣe, ẹgbẹrun mẹwaa obinrin ni mo ti ba lopọ.”

Ṣugbọn agbabọọlu naa sọ fun awọn ọlọpaa pe oun ati awọn obinrin mejeeji jọ fẹnuko lati ni ibalopọ ni, nitori naa, oun ko hu iwa buruku kankan.