Bẹ́ẹ̀ bá ń lo òògùn amú ǹkan ọkùnrin lè fún ìbálòpọ̀ gbígbóná, àrùn rọpa rọsẹ̀ ń bọ̀ o! – NAFDAC

Aworan ọkunrin ati obinrin

Oríṣun àwòrán, © ROYALTY-FREE / CORBIS

Ajọ to n boju to ounjẹ jijẹ ati lilo oogun oyinbo ni Naijiria, NAFDAC ti kilọ pe lilo oogun amu nkan ọkunrin le lati mu ori ololufẹ ya si idan ti wọn fẹ pa, o lee ja si arun rọpa rọsẹ tabi iku.

Oludari agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye sọ lọjọ Aiku pe ọpọlọpọ awọn oogun yii ni ko gba ayẹwo awọn kọja.

“Wọn gba ọna ẹburu ko awọn oogun yii wọ orilẹede ni. To ba jẹ pe wọn fi orukọ silẹ, awọn to n ṣe atawọn to n ta a ko ni maa ṣe ohun ti wọn n ṣe lawọn ile itaja, ori ayelujara ati loju popo”.

Ajọ NAFDAC ni ọpọlọpọ ni ko mọ awọn ipalara ti aṣilo awọn oogun ọhun abi awọn ti wọn ko fi orukọ wọn silẹ. “Nigba too ba n jẹ ki ẹjẹ lọ si apa ibi kan ni agọ ara to si pẹ nibẹ ju bi o ti yẹ lọ, o lee ṣe akoba fun ohun to n pin nkan kaakiri ara”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọgbọn Adeyeye fi kun un pe awọn oogun yii ti wọn mọ si “Aphrodisiacs” tun maa n ba awn ogun mii to wa ninu ara dara pọ to si ni inu ẹdọ ni atupalẹ oogun ti maa n waye ti eyi ti ko dara yoo si jade lara.

“Nigba ti wọn ba lo awọn ogun amu-nkan ọkunrin le yii paapaa ti wọn ba tun pa a pọ mọ oogun ibilẹ eyi ti ko ni odiwọn tabi ọna ati lo o, o lee ba awọn ẹya ara inu jẹ. O lee ba ẹdọ ati kindinrin jẹ eyi to si lee ja si iku fun wọn”.

Oogun amu-nkan ọkunrin le

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gẹgẹ bo ṣe sọ ọ, fun awọn to ni ipenija ilera, bii ẹjẹ riru ati aisan ọkan, wọn maa n ro pe oogun naa le ran ara wọn lọwọ o si lee mu ayipada ba agọ ara ti yoo fa arun rọpa rọsẹ tabi ki ọkan ẹni naa dede dakẹ lati maa mi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Eyi saba maa n ṣẹlẹ bi awọn ọkunrin ba dede ṣubu wọọ lasiko ibalopọ gẹgẹ bi iru eyi ti iroyin gbe to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Rivers ati Cross Rivers laipẹ yii”. Adari ajọ NAFDAC sọ bẹẹ.

Adeleye fi kun un pe, “oriṣiriṣi ipalara lo wa ninu ẹ. Gbogbo ogun lo ni anfani ati jẹ majele. Gbogbo ogun lo ni ipalara kan tabi omiran to lee ṣe fun ara.

O ni nigba miran, agbarijọwọ iṣesi gbogbo ogun to wa lagọ ara lo maa n jẹ eyi si tumọ si pe o lee ja si iku tabi ko ba agọ ara jẹ gidi gidi.

“Kii ṣe gbogbo iku ojiji lo ti ọwọ ajẹ ati oṣo wa lati abule; sugbọn ni ọpọ igba oun ta n jẹ tabi mu lọna to wu wa lo ṣakoba”.