Àwọn alamí ìjọba kan ti wà láàrín àwa ajìjàgbara Yoruba Nation tó ń bínú pé Sunday Igboho ti ga ju àwọn lọ – Akintoye

BAnji Akintoye ati Igboho

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Adari ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua to jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ to n ja fun ominria ilẹ Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti figbe ta pe ijọba orilẹede Naijiria ti gba awọn òǹṣẹ̀ oṣelu kan ati awọn alatako kan to n dibọn bii ọkan lara awọn ajijagbara fun Yoruba Nation.

Ọjọgbọn Akintoye ni “ijọba gba awọn onṣẹ wọnyii lati mọọmọ ba akitiyan ijangbara fun Orilẹede Oduduwa jẹ titi yoo fi di akurẹtẹ”.

O ni awọn aridaju to m’ọgbọn wa to wa niwaju oun fihan pe wọn ti sanwo fun awọn onṣẹ oṣelu yii pẹlu Dollar ati Naira lati gbogun ti oun Akintoye atawọn oluranlọwọ oun pe awọn kọ lati gba ibọde fun ọgọọrọ awọn ọmọ Yoruba.

Akintoye ni awọn abatẹnijẹ ti ijọba sanwo iṣẹ fun yii ti pe fun ipade apero nla kan ni ago meji ọjọ kejidinlogun oṣu kọkanla ọdun 2021 lati ṣebajẹ oun ati lati pa oun lẹnu mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹwẹ, Akintoye ni “gbogbo ete aburu awọn kokoro ajẹnirun lodi si iran Yoruba yii ni yoo pofo, wọn kan n ba itan ara wọn jẹ lasan ni”.

O ni awọn to tọpasẹ ti wọn n tọ yii latijọ ti di ẹni igbagbe bayii to si jẹ pe awọn Yoruba kan n ranti wọn bii Judasi Iskariotu ọdalẹ ni. Ninu atẹjade kan to fọwọ si eyi ti agbẹnusọ rẹ, Maxwell Adeleye fi ṣọwọ si awọn oniroyin, Ọjọgbọn Akintoye ni oun ti faaye gba awọn alatako yii ju ṣugbọn ohun gbogbo toun ba ṣe fun wọn ko tun tẹ wọn lọrun pe gbogbo ohun ti wọn ṣaa n lepa ninu ijijagbara tawọn n ja ni ki wọn le mọ wọn.

“Awọn alatako aarin wa yii ṣe ajọyọ nigba ti ijọba ran ajọ DSS lati lọ ṣe ikọlu si ile Akọgun mi, Sunday Adeyemo Igboho. Wọn o tilẹ fẹ ki o jade kuro lẹwọn nibi ti ijọba Naijiria ti de e ni papamọra lọwọlọwọ ni Benin Republic”.

Ki ni awọn ti Akintoye pe ni onṣẹ ijọba yii n ṣe ninu ẹgbẹ wọn?

Ọjọgbọn Akintoye ni ẹṣẹ ti Sunday Igboho ṣẹ wọn ni pe wọn ni o ti di ilumọọka ninu ijagbara yii ju emi gan lọ.

“Wọn a maa kun yùùn pé awọn ti wa ninu ija fun ilẹ Yoruba yii fun ọpọlọpọ ọdun, eeyan kan to wa ṣẹṣẹ darapọ ni wọn n gbe gẹgẹ bii akinkanju. Mo rọ wọn lati i eleyi gẹgẹ bi ifarajin ati ija fun awọn ọmọ wa ṣugbọn wọ kọ lati gbọ.

“Eyi ti wọn ṣe to buru jai ni igba ti wọn kọ lat ko owo ẹgbẹ to wa ni ikawọ wọn silẹ taa fẹ fi kun owo sisan fun awọn agbẹjọro Igboho ni Benin Republic”.

O ni ọrọ ba di gbọin ti awọn ri nkankan ṣe afigba ti oun lo aṣẹ ati fifun wọn ni ijiya to tọ labẹ ofin ẹgbẹ ti gbogbo eeyan fọwọ si eyi to si mu wọn binu.

Akintoye ni lati igba naa lawọn alatako yii ti n dẹru bolẹ lati da ijijagbara naa ru.

O ni wọn ti bẹrẹ si ni ba oun jẹ ni gbangba lati mu inu awọn to n sanwo wọn dun ni Abuja ati Eko nigba ti awọn ete wọn ko ṣiṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ijọba ti Fulani n dari lo n sanwo wọn to si darukọ awọn ileeṣẹ iroyin meji kan ti wọn sanwo fun lati ṣafihan ipade apero ti wọn fẹ ṣe laago meji o si ni wọn ti fiwe pe awọn oniroyin Naijiria lati wa gbe e sori afẹfẹ.

“Ṣugbọn o da mi loju pe awọn eeyan Yoruba yoo ba awọn kokoro ajẹnirun yii ja. A o ni gba ọjẹgẹ laipẹ yii, wọn si maa mọ pe awọn o pọ to”.

O ni gbogbo ete wọn ni lati da oun lọkan ru amọ oun ti pinu pe oun yoo ja ija yii titi dopin aye oun ni.

O wa n rọ awọn ọmọ Yoruba to jẹ ọdọti ko tii pe aadọta ọdun lati jade fun ija ti ko ni mu iran Yoruba pada si oko ẹru.