“Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí”

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1

Awọn eeyan kan lorilẹ-ede Benin Republic ti ke gbajare si ijọba ilẹ naa lati fi oloye Sunday Igboho silẹ ko lọ tọju ara rẹ nilẹ okeere nitori ara ko ya, aisan naa si lagbara gidi.

Ọkan lara awọn eeyan naa, Agbomola Ajirotutu lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan to fi lede lori ayelujara.

Ninu fidio ọhun lo ti ke sita pe oloye Sunday Igboho ko gbadun, o si yẹ ki awọn alẹnulọrọ ni Benin Republic da si ọrọ naa ki ijọba ilẹ ọhun le jọwọ rẹ lati lọ tọju ara rẹ ko ma baa ku silẹ awọn.

O ni “Ẹyin olowo ati ọlọrọ orilẹ-ede Benin ti ẹ gbọ Yoruba, gbogbo wa la mọ pẹ wọn mu oloye Sunday Igboho to jẹ ọmọ Naijiria si atimọle lorilẹ-ede wa nitori o fẹ gba orilẹ-ede wa kọja lọ silẹ mii.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ara rẹ ko ya bayii, aisan naa si lagbara gidi… Ẹyin gbajumọ ati ọlọrọ Benin, ẹ ẹ sì dahun si ki wọn gbe ọrọ yii kuro lẹyinkule wa nitori nkankan ko gbọ ṣe baba yii ni orilẹ-ede wa.”

Ajirọtutu tẹsiwaju pe “Ẹ dide ki ẹ sọrọ soke ki wọn fi ọkunrin yii silẹ ko maa ba ti ẹ lọ, nitori ko si ohun to kan wa ninu ọrọ wọn.”

Ọkunrin ọhun sọ siwaju si pe o ṣeeṣe ki gudugbẹ ja ni Benin Republic, ti Igboho le ba ku si orilẹ-ede naa.

O tun rọ awọn ọmọ ilẹ ọhun lati tẹ mọ ijọba ilẹ naa leti pe ko fi Igboho silẹ nitori ti ajijagbara naa ba le dakẹ silẹ awọn, awọn ọmọ ilu naa ni yoo fori fa rogbodiyan to ba ti ẹyin rẹ jade.

Lẹyin naa lo ni alaafia lo ṣe koko ati pe ẹmi ko laarọ, o ni o yẹ ki wọn jẹ ki Igboho tọju ara rẹ ki wọn to tẹsiwaju ninu igbẹjọ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Amofin Yomi Aliyu ní igbẹ́yin Sunday Igboho ko gbọ̀dọ̀ da bi ti Busari Adelakun, ko si gbọ̀dọ̀ ku

Ẹwẹ, ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho to wa ni Naijiria, Yomi Aliyu naa tun fidi ọrọ naa mulẹ lori ikanni WhasApp rẹ, eyii ti BBC Yoruba foju ganni pe lootọ ni Igboho ti wa nile iwosan.

Ohun ti Yomi Aliyu kọ soju Whatsapp rẹ

Oríṣun àwòrán, Yomi Aliyu

Aliyu ni “Oloye Sunday Igboho n ṣaisan gidi, o si ti wa nile iwosan bayii.”

“Ẹ jọwọ ẹ ba wa fi adura ranṣẹ si, ki igbẹyin rẹ ma baa da bii ti Oloye Adelakun Eruobodo, Igboho ko gbọdọ ku o!.”