Àlàyé rèé lórí ipa tí ogun Israel àti Iran yóò ní lára Naijiria

Gaza

Oríṣun àwòrán, getty images

  • Author, Olumide Owaduge
  • Role, BBC Journalist
  • Reporting from Lagos

Onimọ nipa ohun to n lọ lagbaye, to tun jẹ amofin ati ajafẹtọ ọmọniyan, Dele Farotimi ti sọ pe wọn n ja nile keji ko kan mi ni ọrọ ogun Iran ati Israel yẹ ko jẹ si Naijiria.

Farotimi sọ pe ko yẹ ki ọrọ ado oloro to n fo laarin orilẹ-ede mejeji kan Naijiria gbọngbọn amọ o ni ipa to le ko ni Naijiria.

Amofin naa lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

O ni “ọrọ wọn, oyun were ni, ko na mi ni kolo bi awọn baba wa ṣe maa n wi, ija ile keji ni, ko kan mi.”

Ipa ti ija naa le ni lara Naijiria

Farotimi tẹswiwaju pe ija naa le mu ki epo rọbi gbowo lori, eyii to le ṣakoba fun ọrọ aje Naijiria.

O ni “idi ti a ko fi le ni ija naa ko kan wa rara ni pe nigba ti wọn ba da agbegbe Middle East ru, ti epo bẹrẹ si n gbowo lori.

“Laye igba kan, ti epo ba gbowo lori, bi igba ti maalu so ipa ni, idunnun alapata, ṣugbọn laye ode oni ti a ko le fọ epo wa, to jẹ pe niṣe ni a n ko epo wọle lati ilẹ okeere, wahala ni yoo jẹ fun wa ti rogbodiyan ba bẹ silẹ ni Middle East.

O ni to bẹ jẹ aye atijọ ni, idunnu Naijiria ni yoo jẹ ti wọn ba n ja nitori Naijiria yoo ri owo epo pa wọle .

Gẹgẹ bii ohun to sọ, lode oni, bi epo rọbi ṣe n gbowo lori lagbaye naa ni epo bẹntiro n gbowo lori ni Naijiria, eyii si le ṣakoba fun ọrọ aje Naiijiria.

Amofin naa ṣalaye siwaju si pe Naijiria ko ri epo rọbi ko jade mọ bii ti tẹlẹ mọ latari bi awọn kọlọrọsi kan ṣe n ji epo rọbi naa ko lati ta fun anfani ara wọn nikan.

Ṣe o ṣeeṣe ki ogun Iran ati Israel da ija ẹsin silẹ ni Naijiria?

Ninu ọrọ Farotimi, ẹni ti ko jẹ gbi ko yẹ ko ku gbi, ko yẹ ki ọrọ naa kan Naijiria gbọgbọn to ba jẹ pe ijọba Naijiria ṣe awọn ohun to yẹ ni.

Ni ti ija ẹsin ti awọn kan n woye pe o ṣeeṣe ko waye ni Naijiria latari ọrọ naa, Farotimi sọ pe ainironu ni yoo jẹ ki awọn eeyan maa ba ara wọn ja ni Naijiria lori ọrọ ẹsin nitori ija to n waye laarin orilẹede meji to wa nilẹ okeere.

O pari ọrọ rẹ pe “to ba di ogun agbaye, ko kan wa.”