Àlàyé lórí bí Báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN ṣe tako ara rẹ̀, ó ní òun kò ní kí àwọn báńkì ó gba N500 àti N1000 àtijọ́ lọ́wọ́ aráàlú

Aworan owo N1000 atijọ ati owo tuntun

Oríṣun àwòrán, other

Banki apapọ Naijiria, CBN ti sọ pe oun ko ni ki banki kankan bẹrẹ si nii gba owo naira ẹẹdẹgbẹta naira N500) ati ẹgbẹrun kan (N1000) pada lọwọ araalu.

Banki apapọ CBN sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita loju opo ayelujara rẹ pe aṣẹ aarẹ Buhari to fi sita ninu ọrọ rẹ lọjọbọ pe igba naira nikan ni ki wọn da pada sigboro lawọn n tẹle.

Ṣaaju, lọsan ọjọ Ẹti ni iroyin kan ti bọ si igboro pe banki apapọ Naijiria, CBN ti paṣẹ fun awọn banki pe ki wọn bẹrẹ si nii gba owo ẹẹdẹgbẹta naira olodindi (N500) ati ẹgbẹrun kan naira olodindi (N1000) pada lọw araalu.

Nibo ni aṣẹ akọkọ to ni ki awọn banki maa gba Bawo ni aṣẹ akọkọ to ni ki awọn banki o gba N500 àti N1000 ti wa?

Iroyin kan to n kaakiri lọsan ọjọ Ẹti sọ pe Banki apapọ Naijiria ti fun awọn banki laṣẹ lati maa gba owo naa pada lọwọ araalu.

Awọn iwe iroyin abẹle kan tilẹ sọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ banki apapọ CBN kan fidi aṣẹ naa mulẹ.

Ẹwẹ ninu ọrọ to ba BBC News Pidgin sọ, alukoro banki apapọ, ọgbẹni Osita Nwanisobi sọ pe aṣẹ ti jade si awọn banki naa lati maa gba owo naa pada.

Awọn eeyan pẹlu owo atijọ to ku lọwọ wọn

Koda nigba ti akọroyin BBC News to ba sọrọ bii pe ki lo wa de ti awọn banki kan ṣi n kọ owo naa, ọgbẹni Osita Nwanisobi to ni ilu Umuahia loun wa lasiko ifọrọwerọ naa ṣalaye pe, “awọn alṣẹ lati olu ileeṣẹ banki bẹẹ ni yoo fi aṣẹ ti banki apapọ pa fun wọn naa ṣọwọ si gbogbo ẹka wọn. Atipe ni ilu Umuahia ti mo wa bayii, awọn banki n gba owo naa pada.”

Lati fi idi iroyin lori aṣẹ yii mulẹ, atẹjade loju opo ayelujara awọn banki kan fi idi aṣẹ yii mulẹ. Fun apẹrẹ loju opo ayelujara ile ifowopamọsi First Bank, ati

CBN gbe aṣẹ tuntun jade

Lẹyin awuyewuye yii ni banki apapọ CBN gbe atẹjade miran jade pe irọ ni iroyin naa ati pe oun ko ni ki awọn ile ifowopamọsi maa gba owo owo ẹẹdẹgbẹta naira olodindi (N500) ati ẹgbẹrun kan naira olodindi (N1000) pada lọw araalu.

Alukoro CBN Osita Nwanisobi to ti kọkọ ba BBC News sọrọ pe lootọ lawọn banki ti n gba owo naa pada lo fi ọwọ si atẹjade ọhun eyi to ni aṣẹ aarẹ lori igba naira olodindi nikan lawọn n tẹ le. Atẹjade naa wa rọ awọn araalu lati keti ọgbọin si ọrọ yoowu ti ko ba ti ọdọ banki naa jade.