Akúṣẹ́ apẹja bọ́ sínú agbami ọrọ̀ lẹ́yìn tó rí èébì ẹja Wéèlì létíkun

Eebi ẹnu ẹja Weeli

Ti a ba n gba adura si Eleduwa pe ‘mu mi ṣe kongẹ oore lẹnu iṣẹ mi’, a fi ka yara ṣe amin adura naa ni kia.

Idi ni pe adura yii ti gba fun arakunrin apẹja kan to ko oore ẹgbẹlẹgbẹ dọla owo ilẹ Amẹrika lẹnu iṣẹ ẹja pipa.

Apẹja ni arakunrin Narong Phetcharaj lorilẹede Thailand, ki ori to gbe e ko ire nigba to ri eebi ẹja abubutan Weeli, ti iye rẹ to miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba dọla owo ilẹ Amẹrika he, leti okun Niyom,

Iroyin sọ pe, ṣaaju, oju to n pọn igún apẹja yii kii ṣe kekere nitori iṣoro nla ni ọrọ jijẹ mimu fun oun atawọn ẹbi rẹ.

Lẹyin to ri eebi ẹja Weeli naa he tan lo ba fi lọ awọn akọṣẹmọṣẹ ni ileewe fasiti Prince of Songla University.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn ni wọn ṣe iwadi ti wọn si ri aridaju pe ambergris, iyẹn eebi latẹnu ẹja Weeli ni eroja naa, to si jẹ wi pe ohun ni wọn fi n ṣe ororo itura oloorun didun pafuumu olowo iyebiye.

Kini ọhun to le bi okuta, eyi ti ọpọ n da pe ni “goolu to n lefo loju omi” ni wọn ni iye rẹ to ẹgbẹrun marundinlogoji ni iwọn kilo kan.

Iwọn ọgbọn kilo eebi ẹja abubuutan Weeli naa ni apẹja yii ri leti okun, ti ireti si wa pe yoo lanfani ati taa lowo ti yoo to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu dọla owo ilẹ Amẹrika.

Ẹya ẹja Weeli ti wọn n pe ni “Sperm Whales” lo maa n pọ eebi yii; bi eebi yii ṣe tobi to si tun wuwo to, ori omi lo maa n lefoo si, tabi ki ọwọ iji omi o gba a wa si etikun.

Bi eebi yii ba ti wa gbẹ tan ni yoo wa di ohun oloorun didun eleyi ti awọn onimọ sọ pe awọn akọṣẹmọṣẹ n wa kiri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Saaju ni ọdun yii, awọn apẹja kan naa ṣe kongẹ eebi ẹja abubutan Weeli yii ni erekuṣu Aden nitosi agbami Yemen. Nigba ti wọn la gogongo ẹja naa, ni wọn ri kini nla naa to le kokoko, to hun jọ si ọna ọfun rẹ.

Si iyalẹnu wọn, miliọnu kan o le ọgọrun ẹgbẹrun dọla ni wọn taa ti wọn si pin owo naa laarin ara wọn ti wọn si tun pin lara rẹ fun awọn to ku diẹ kaato fun ni ileto wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi iwadi ijinlẹ latọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ ṣe sọ, inu ifun iwọn ida kan si marun un awọn ẹya ẹja Weeli ti wọn n pe ni Sperm Whales yii ni o ti maa n jade.

Ọkan lara awọn apẹja naa ṣalaye fun BBC pe, “A pinnu lati fi iwọ mu ẹja Weeli naa, a gbe e wa si eti okun nibi ti a ti gee lati mọ nnkan to wa ninu rẹ. Ki n ma tan yin, eebi ẹja yii lo wa ninu rẹ.”

O fi kun un pe, “oorun rẹ ko dara rara, ṣugbọn owo gọbọi lo ba de.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ