Àjọ NDLEA yabo ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó, wọ́n mú ọkọ ìyàwó àtàwọn ọ̀dọ́ míì lórí egbò igi olóró

Aworan awon odo

Oríṣun àwòrán, NDLEA/X

Awọn osisẹ ajọ to n gbe ogun ti lilo egbogi oloro nipinlẹ Kaduna da igbeyawo kan ru lẹyin ti iroyin tẹwọn lọwọ pe idije lílo egbogi n waye.

Igbeyawo naa lo waye ni agbegbe Shola Quarters nipinlẹ Katsina, ti wọn si mu ọdọ medọgbọn to kopa ninu idije lílo egbogi oloro.

Agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babalola lo kede ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.

O ni awọn osisẹ mu awọn afurasi lasiko ti wọn lo awọn egbogi oloro pẹlu orisirisi awọn nnkan mii ninu ìke.

“Botilẹ jẹ pe ọkọ ìyàwó, Musa Gwandi to da ayẹyẹ naa silẹ ko si ni ibi tí wọn ti mu awọn ọrẹ rẹ mẹdọgbọn.”

Bakan naa ni Ajọ NDLEA to wa ni papakọ ofurufu Akanu Ibiam nipinlẹ Enugu gbegi dena egbogi oloro kan to jẹ ti ileeṣẹ egbogi oloro.

Onisowo kan, Augustine Justine Emeka, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, ní onisowo waya ni oun ni ọwọ tẹ ni papakọ ofurufu naa lasiko to n bọ lati Douala lorilẹede Cameroon to si ba Ọkọ baalu Addis Ababa de pẹlu egbogi oloro naa.

O jẹ wọ pe egbogi oloro naa lo wa fun eeyan mejila kaakiri orilẹede Naijiria.