Àìsàn tó ń ṣe ọ ní ohun ṣe pẹlú oorun rẹ – Onímọ

Awọn eeyan to n sun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“To ba fẹ ni ẹmi gigun, ati ilera to peye, o ko gbọdọ yan oorun lodi rara, o si gbọdọ maa ba oorun sisun se ọrẹ ni.”

Eyi ni ero onimọ kan nipa ihuwasi ẹda ati imọ sayẹnsi nipa ọpọlọ, Matthew Walker, to wa lsgba fasiti California.

Awọn onimọ ni oorun ni oogun to jẹ ọfẹ julọ, eyi to lee fun ara rẹ ni ilera to peye julọ, lẹyin iwadi imọ ijinlẹ to le ni aadọta ọdun, wọn ko lee beere mọ nipa awọn ohun ti oorun sisun lee mu wa fun wa, bikose pe ka beere pe, n jẹ nkankan wa ti oorun sisun ko lee se fun wa?

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iwadi ti wa fidi rẹ mulẹ pe, aisun maa n ni ipa to buru julọ lori ọpọlọ ati ẹya ara wa.

Gbogbo awn aisan bii jẹjẹrẹ, aisan ọkan, ara asanju, atọgbẹ, ironu ati iwa gbigba ẹmi ara ẹni, to maa n tete ran awọn eeyan sọrun ni awọn orilẹede to ti goke agba lagbaye, lo ni nkan se pẹlu oorun sisun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Amọ, oorun yii gbọdọ wa funra rẹ ni, kii se afioogun pe, eyi to lee sokunfa aisan jẹjẹrẹ, kokoro ti a ko lee fi oju ri ati iku aitọjọ.

Oorun sisun kii se ka gbe ori le irọri nikan, tori kii se ọpọ eeyan lo lee tete sun lati ipasẹ eyi nikan

Sugbọn awọn onimọ ni ta ba lee mu ayipada ba awọn iwa kan to ti di baraku fun wa, a maa sun bo se yẹ:

Ọmọ ati iya rẹ to sun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bawo la se fẹ ri oorun gidi sun ni alẹ:

  • Maa ji, ko si maa sun ni akoko kan naa lojoojumọ –

To ba lee maa ji, ko si maa sun ni akoko kan naa lojoojumọ, eyi too ran ọ lọwọ lati maa mọ iye wakati to fi n sun, ti oorun yoo si maa kun ọ, ti akoko to yẹ ko sun ba ti ko.

  • Fi ara rẹ sinu okunkun –

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

A nilo lati wa ninu okunkun, ki ara si balẹ, ki omoonu kan, ti wọn n pe ni Release Melatonin, to n fa oorun sisun, lee sisẹ rẹ.

Sugbọn ọpọ wa la n gbe ni ayika ti imọlẹ ti yi wa ka, sugbọ o le seranwọ fun ara rẹ nipa mimu adinku ba imọlẹ to wa ni ayika rẹ, nigba to ba ku wakati kan to fẹ sun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Fi ara balẹ lori ibusun lai maa yi kaakiri –

Jẹ ki ibusun rẹ sun nipa ko ma yi kaakiri tabi maa ba irọri rẹ ja

  • To ba sun sori ibusun, ti oorun ko ba wa, dide nilẹ, ko maa se nkan miran bii kika iwe tabi rin kaakiri

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

  • Se adinku awọn eroja amu oorun da loju ẹni bii, obi ati ‘Coffee’, ki orun lee tete wa
  • O nilo wakati mejila ki eroja kọffi to lee kuro ni ara rẹ, tori naa, ma mu ksffi tabi jẹ obi lọwọ irọlẹ.
  • Sọra fun ọti lile. Lodi si ero ọpọ eeyan, ọti lile kii mu oorun kun eeyan tabi mu ki ara balẹ., o si tun lee se akoba fun ala ati oorun rẹ.