Afenifere pé fún ìfìyàjẹ àwọn Afurasí Oodua Nation tó yá wọ ọgbà ọ́físì Gómìnà Oyo

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/Nigerian Army

Ẹgbẹ Afenifere ile Yoruba ti bu ẹnu atẹlu bi awọn ikọ ajijagbara Oodua Nation ṣe ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ lọsẹ to kọja.

Afenifere, ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa, Comrade Jare Ajayi fi lede fun awọn akọroyin, salaye pe awọn to lọwọ ninu ikọlu gbe igbesẹ naa ni ọna ti ọpọ ọmọ Yoruba ti wọn ni awọn n soju lodi si.

O ni ijọba ni lati ṣe iwadi, ko si fiya jẹ wọn ni ilana ti ofin gbekalẹ lati le jẹ ẹkọ fun awọn eeyan mii to ni erongba irufẹ bẹẹ

Bẹ ba gbagbe, ọjọ Satide ọsẹ to kọja ni awọn eeyan kan to pe ara wọn ajijagbara Yoruba Nation yawọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ni Agodi, ti wọn sapejuwe gẹgẹ bii olu ilu fun Ilẹ Yoruba.

Sugbọn Afenifere ni ko si nnkan to jọ mọ orilẹede Ilẹ Yoruba ni bi kibi.

“Ile Yoruba jẹ ilu kan gboogi to wa labẹ orilẹede Naijiria. Gẹgẹ bii a se mọ, ko si nnkan to n jẹ ominira”

Lọwọ lọwọ bayii, awọn eeyan Yoruba wa ni ipinlẹ Ekiti, Eko, Ogun, Ondo, Osun ati Oyo.

Bakan naa ni wọn ni awọn apa ibi kan ni Kwara, Kogi, Delta ati Edo.

Ajayi ni ọpọ iwa ibajẹ lo wa ni ọna ti awọn oloselu fi n da ri orilẹede Naijiria.

“Ọna abayọ si awọn iṣoro yii ki ṣe jagidijagan. Ohun to yẹ ka ma ja fun ni pe ka wa bi a ṣe wa ọna abayọ si iṣoro orilẹede yii.

“Afenifere si ni igbagbọ ninu iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu to n sapa fun Naijiria ati awọn olugbe rẹ lati ma gbe papọ ni alafia laipẹ.”

Afenifere ni ilana ti awọn ikọ ajijagbara yii gunle ni ko mu ọpọlọ dani rara.

“Bawo ni eeyan kan tabi ẹgbẹ kan ma ro pe ti awọn ba ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ tumọ si pe awọn ti da idasilẹ orilẹede mii.

“Yoruba ma ronu ki wọn to gbe igbesẹ papa irufẹ igbesẹ bayii. Yoruba ko ki n gbe igbesẹ ni ilana yii.

“Wọn yoo ro ori wọn ki wọn to ni awọn gunle nnkan bayii.”

Agbẹnusọ Afenifere wa pe fun iwadi, to si rọ ijọba lati fiya jẹ awọn afurasi naa ni ilana ti ofin gbe kalẹ, eyi to ni yoo jẹ ẹkọ nla fun awọn eeyan mii to ni irufẹ erongba kanaa.”