Adeleke gbégi dí àsùwọ̀n owó ìjọba Osun

Gómìnà Ademola Adeleke

Ní kété tí wọ́n búra wọlé tán fún Ademola Adeleke gẹ́gẹ́ bí i gómìnà kẹfà ìpínlẹ̀ Osun ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yẹ ò sokà.

Lẹ́yìn náà ló sì ti pàwọn àṣẹ kan láti tẹ ìpínlẹ̀ náà síwájú gẹ́gẹ́ bí èrò rẹ̀.

Gómìnà Adeleke ní láti ìgbà tí àjọ elétò ìdìbò INEC tí kéde òun bí i ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbì ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Keje ọdún 2022 ni gómìnà àná Gboyega Oyetola ti ń wá gbogbo ọ̀nà láti mú kí ìṣèjọba nira fún òun.

Adeleke nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n búra fun tán ní lára ìgbésẹ̀ tí Oyetola gbé ni gbígba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn síṣẹ́ láì sí bí wọ́n yóò se san owó fún wọn nínú àbá ìsúná.

Ó ní fún ìdí èyí òun ti gbégi dí gbogbo akoto owó ìjọba Osun fún ìgbà kan ná.

Ó ní kò ní sí ààyè fún kí owó jáde nínú àsùnwọn ìjọba títí àwọn ìwádìí àwọn kan yóò fi parí.

Bákan náà ni Adeleke tún yí orúkọ ìpínlẹ̀ Osun kúrò ní “State of Osun” padà sí “Osun State” wí pé èyí tí ìjọba ń pè é náà kò bá ìwé òfin Nàìjíríà mu.

Lára àwọn ẹ̀sùn tí Adeleke tún fi kan Oyetola ni pé ó yan àwọn kan láì gba àwọn ọ̀nà tó tọ́ èyí tó fẹ́ fi dá wàhálà kalẹ̀ sí ìjọba òun lọ́rùn.

Oyetola kọ̀ láti gbé ìwé “ibi mo báṣẹ́ dé” lémi lọ́wọ́ – Adeleke

Adeleke ṣàlàyé pé gbogbo ìgbìyànjú òun láti rí wí pé Oyetola gbé ìjọba kalẹ̀ fún òun lọ́nà tó tọ́ àti bó ṣe yẹ ni Oyetola gbégi dínà.Ó ní kò sí ìwé àkọ́lẹ̀ kankan tí Oyetola gbé fún òun láti fi ṣàlàyé ibi tí wọ́n bá ètò ìjọba dé ní ìpínlẹ̀ Osun nítorí náà kí àwọn ènìyàn ṣe sùúrù pẹ̀lú òun.

Ó tọrọ ọ̀sẹ̀ díẹ̀ láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ètò ìjọba fún ìgbà kan náà kí ìjọba òun le mọ ibi tí àwọn yóò ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

Ademola Adeleke

Àwọn àṣẹ mìíràn tí Adeleke tún pa yàtọ̀ sí gbígbégi dí akoto ìjọba àti yíyí orúkọ ìpínlẹ̀ náà padà ni:

Ṣíṣe àgbédìde ìgbìmọ̀ tí yóò wá láti gba gbogbo àwọn ohun ìní ìjọba tó wà ní lọ́wọ́ àwọn padà sábẹ́ àkóso ìjọba.

Ṣíṣe àgbédìde ìgbìmọ̀ tí yóò ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo ìgbanisíṣẹ́ àti àwọn ìgbésẹ̀ tí ìjọba àná gbé láti ọjọ́ Kẹtàdínlógún tí INEC ti kéde rẹ̀ bí i ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò.

Bákan náà ló ní gbogbo àwọn pátákó tàbí àwòrán tí wọ́n bá ti ń kọ orúkọ ìpínlẹ̀ Osun sí ni kí wọ́n yí orúkọ rẹ̀ padà sí Osun State dípò State of Osun tí ìjọba àná ń kọ.

Adeleke ni ìjọba òun yóò gbájúmọ́ ṣíṣe àgbédìde ètò ọ̀gbìn, ètò ẹ̀kọ́, ìnàjú, mímú ìdàgbàsókè bá àwọn obìnrin àti ọ̀dọ́, ètò ìlera, àyípadà ojú ọjọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.