À ń wá Gbajúmọ̀ apanilẹ́ẹ̀rín, Cute Abiola o! A kò gbúrò rẹ̀ nílé – Mọ̀lẹ́bí

Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Cute Abiola

Gbajugbaja apanilẹrin, Abdulgafar Ahmad Oluwatoyin, ti awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Cute Abiola ti di àwátì.

Oluwatoyin to tun jẹ ọmọ ogun ori omi, ni akẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ awada ṣíṣe, Mr Macaroni, kede loju opo Twitter rẹ pe ẹbi ati ọrẹ rẹ n wa.

Cute Abiola

Oríṣun àwòrán, Mc ALways

Ikede naa sọ pe ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdogun, oṣù Kọkanla, ni iyawo Cute Abiola ati awọn alajọṣiṣẹpọ rẹ ti gburo rẹ kẹhin.

Iroyin sọ pe ni nkan bi aago mẹfa owurọ ọjọ naa lo kuro nile, lati lọ si ibi isẹ rẹ nileeṣẹ ọmọ ogun ori omi. O de ibi isẹ ni nkan bi aago meje, o si pe iyawo rẹ lati jẹ ko mọ pe oun ti de ọfiisi.

Lati igba naa si ni oun ati awọn alajọṣiṣẹpọ ti gburo rẹ mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Lẹyin to pe iyawo ati awọn alajọṣiṣẹpọ rẹ pe oun ti de ibi iṣẹ, ko ti i pada sile lọdọ ẹbi rẹ, bẹẹni ẹnikẹ́ni ko gburo rẹ titi di asiko yii.”

Ṣugbọn sa, iroyin kan ti a ko tii fidirẹmulẹ sọ pe inu ahamọ ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi lo wa lati igba to ti de ibi isẹ lọjọ Aje.

Bẹẹni ko si ẹni to mọ ẹ̀sùn ti wọn fi kan an, eyi to gbe de atimọle.

Iroyin naa tun sọ pe lati olu ileeṣẹ ologun naa ni àṣẹ ti wa pe ki wọn o fi Cute Abiola si ahamọ.

Ni odun 2020, ileeṣẹ ologun ori omi ti fi si ahamọ ri, “nitori pe o fi aṣọ ologun ya aworan ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, to si tun fi aworan naa sori ayelujara Instagram.

Taa ni Cute Abiola?

Ọmọ ilu Ilorin, nipinlẹ Kwara ni Abdulgafar Ahmad Oluwatoyin.

Ọdun 1996 ni wọn bi.

O si ti bẹ̀rẹ̀ isẹ apanilẹrin lati kekere. Sugbon o di ilumọọka lati ọdun 2015.

Oṣù Karun-un, ọdun 2021 lo ṣe igbeyawo.

Òṣìṣẹ́ ọmọ ogun ori omi Naijiria, Nigerian Navy ni.

Bakan naa lo tun jẹ apanilẹrin ati oṣere ori itage.