World AIDS Day: Ọmọ Nàìjíríà 1.8m ló ń gbé pẹ̀lú ààrùn HIV

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ajọ to n risi igbogunti aarun HIV/Aids ni Naijiria, NACA ti ni o kere tan ọmọ Naijiria to fẹrẹẹ to miliọnu meji ni wọn n gbe pẹlu aarun HIV ti o ma n fa AIDS.

Iwadii yii n suyọ ni Ọjọ Kini, Oṣu Kejila, ọdun 2022 ti wọn n ṣe ayajọ ọjọ ilanilọye nipa aisan HIV lagbaye.

Bi o tilẹ jẹpẹ niṣe ni aisan yii n dinku ni agbaye, ọrọ ko ri bẹẹ fun orilẹede Naijiria

”Awọn eniyan to n ko aarun HIV n pọsi ni Naijiria ni’’

Ajọ NACA ni kaka ko san lara orilẹede Naijiria nipa aarun HIV, nise ni iye awọn to n ko aarun naa ni Naijiria n pọ sii.

Ajọ ọhun ni kaakiri Naijiria ni aarun ọhun ti peleke si.

Ajọ naa ni ijọba apapọ ti na biliọnu mejidinlogun lori gbigbogun ti aarun yii.

Ninu ọrọ tiwọn ajọ iṣọkan agbaye to n risi ọrọ aisan AIDS (UNAIDS) ni eniyan 650,000 lo ku nitori arun AIDS.

Amọ wọn tun fikun un pe eniyan miliọnu kan aabo lo tun ṣẹṣẹ lugbadi aarun naa ti ida meji ninu mẹta si jẹ lati ilẹ Africa.

Bakan naa ni Ajọ UNICEF ni o kere tan eniyan 190, 950 lo n lugbadi aarun HIV ni ọdọọdun ni Naijiria, eleyii to jẹ ikeji to pọjulọ ni agbaye.