Wọ́n ti fi ẹ̀sùn míì kan Sunday Igboho ní ìlú Benin! – Agbẹ́jọ́rò Igboho

Igboho ati Agbẹjọro rẹ

Niwọn igba ti igbẹjọ ajafẹtọ to n ṣaju awọn to n pe fun orilẹede Yoruba Nation, Sunday Igboho ti jẹ atilẹkunmọri ṣe gẹgẹ bo ṣe waye ni Cotonou, BBC Yoruba ti kan si agbẹjọrò Oloye Sunday Igboho lati tu iṣu de isalẹ koko.

Gbogbo ohun ti wọn ninu ile ẹjọ pata ni agbẹjọrò, David Salami ṣe lalaye fun akọroyin BBC to wa ni Cotonou.

Lakọkọ, adajọ ni pe “ọ̀nà ẹ̀yin ni Sunday Igboho gba wọle si orilẹede Benin Republic”, wọn fi ẹsun eyi kan an.

Wọn tun ni gbogbo awọn ti wọn jọ gbimọ pọ pẹlu Igboho to fi ri ọna ẹyin wọ Cotonou patapata lawọn yoo wadii daadaa.

Lafikun, wọn fẹ mọ boya “ṣe irin ọjọ kan pere naa lo rin laarin orilẹede Naijiria si Benin abi o ti wa ni Benin tipẹ to ti n ṣe eto wẹrẹ wẹrẹ.

Wọn tun roo pe “ṣe kii ṣe pe awọn ti wọn jọ gbimọ pọ ọ̀hun n gbiyanju ati wa da orilẹede Benin ru”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gẹgẹ bi agbẹjọro rẹ ṣe sọ, ẹsun ti wọn i kan tẹlẹ ni wọn ti gbékalẹ lóri ọrọ Naijiria.

Ẹsun tuntun ti wọn fi kan ni pe o gba ọna ẹyin wọ orilede Cotonu, sugbọn lẹyin ti wọn bi oloye Sunday Igboho, o ni ọjọ kan pere naa ni oun ṣẹsẹ lo.

Ni asiko yii ni adajo sọ pe àwọn fẹ se iwadii nkan ti o sọ yii, yala o ṣe ipade pẹlu ẹnikẹni ni asiko to wọ ilu tabi ọdọ talo de siKini awọn nnkan to ṣe lasiko to de Èyi lo si fa ti wọn fi ni ki o lọ wa ni ahamọ naa lọgba ẹwọn.

Igboho ati Agbẹjọro rẹ

Sugbọn ni bayii, agbẹjọro rẹ David Salami sọ pe igbesẹ tuntunti awọn yoo ṣe bayii ni lati lọ tgba oniduro rẹ titi ti iwadii yoo fi pari.

Awọn yoo si gba ọjọ lọwọ adajọ lati mọ asiko ti wọn yoo tun pe sile ẹjọ fun igbẹjọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ