Wo ohun tí omi kànga Zamzam nílùú Mecca túmọ̀ sí nínú iṣẹ́ Hajj

Awọn alalahaji n mu omi Zamzam ni Mecca

Oríṣun àwòrán, AFP

  • Author, Jannatul Tanvi, BBC News Bangla
  • Role, BBC News Bangla

Kanga Zamzam wa ninu mọṣalaaṣi nla Masjid al-Haram niluu Mecca ni orilẹede Saudi Arabia.

Mọṣalaasi yii ni o tobi julọ lagbaaye ti o ṣi wa ni ayika Kaaba to jẹ ibi mimọ julọ ninu ẹsin Islam.

Omi Zamzam yii ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn ẹlẹsin musulumi gbagbọ pe o lagbara, o ṣi maa n ṣe iwosan.

Lilọ sibi si idi kanga yii jẹ ọkan pataki alara iṣẹ alalahaji eleyii to fẹẹ jẹ pe gbogbo awọn to lọ fun iṣẹ Hajj lo maa n bu omi naa lọ sile lati Mecca.

Ọpọ awọn ẹlẹsin musulumi to ba lọ si Mecca lo maa n fawọn ẹbi wọn ni omi yii tori wọn gbagbọ pe omi yii lagbara leti wẹ ewu danu lori ẹnikẹni to ba lo o.

O kere tan, eeyan to le ni miliọnu meji ni akọsilẹ sọ pe o yẹ ko wa ni Hajj ti ọdun yii, bo tilẹ jẹ pe awọn kan n sọ pe wọn ju bẹẹ lọ tori ọpọ alejo ni wọn sọ pe ko forukọ silẹ pẹlu ijọba Saudi Arabia.

Bakan naa ni iroyin kan tun sọ pe ọpọ awọn ọmọbibi Saudi gan an lo rinrin ajo lọ si Mecca yala lori omi tabi lori ilẹ.

Awọn alalahaji n mu omi Zamzam ni Mecca

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wo iṣepataki omi Zamazam sawọn musulumi

Omi Zamzam yii ṣe pataki sawọn musulumi tori o jẹ ọkan gboogi lara ọpakuntẹlẹ ẹsin musulumi.

Onimọ nipa ẹsin islam kan, Imaamu Bukhari Abdullah Ibn Abbasṣe akọjọpọ ”hadith” mẹfa kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Sahih al-Bukhari lọdun 860.

Haditii lo tun tẹle iwe mimọ Koran gẹgẹ bi ohun to n tọ awọn musulumi sọna.

Gẹgẹ bi igbagbọ awọn musulumi, Hadiiti jẹ awọn aṣa, iṣesi ati ẹkọ ojiṣẹ Ọlọrun, Muhammad ti awọn to sun mọ an ṣe kọ ọ silẹ.

Ẹwẹ, oju ọtọọtọ ni ẹgbẹ musulumi Sunni ati Shia fi ri hadiiti yii.

Igbagbọ awọn musulumi ni pe, Ọlọrun lo pese kanga Zamzam ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹyin gẹgẹ bi idahun si adura Hajara(to ti i ṣe iyawo ojiṣẹ Ọlọrun Abrahamu) nigba to wa ninu igbo pẹlu ọmọ rẹ laisi oinjẹ tabi omi lati mu lẹyin ti Abrahamu le e wi pe ki o maa lọ.

Itan yii wa ninu Surah Ibrahim ninu Koran eyi to si tun wa ninu awọn iwe nipa ẹsin musulumi mii.

Sahih al-Bukhari ṣalaye bi Hajara ṣe sare fun meje laarin oke Safa si oke Marwa ti o n wa omi ki angẹli Geburẹẹli to fọwọ lulẹ ti omi fi jade.

Nigba ti Hajara n bẹru wi pe omi naa le gbẹ pada ni o sọ pe ”zam zam” eyi to tumọ si pe omi naa le ma ṣan mọ.

Nibi ni orukọ omi naa ti ri orukọ rẹ to fi n jẹ omi Zamzam.

Arinrin-ajo Hajj n mu omi Zamzam

Oríṣun àwòrán, AFP

Kinni ibaṣepọ omi Zamzam pẹlu iṣẹ Hajj?

Iṣepataki omi Zamzam si iṣẹ Hajj jẹ ohun to jinlẹ gan an.

Fun awọn musulumi, iṣẹ Hajj jẹ opo karun un tii ṣe opo to kẹyin ninu ẹsin islam.

Gbogbo musulumi ti o ba ti dagba ti o ṣi lagbara lati ran ara rẹ lọ si Mecca gbọdọ gbiyanju lati lọ sibẹ o kere tan lẹẹkan ni gbogbo ọjọ aye rẹ.

Lẹyin ti o tun Kaaba kọ tan ni ojiṣẹ Ọlọrun Ibrahim pe awọn eeyan wi pe ki wọn wa ṣiṣẹ Hajj gẹgẹ bi ọgagba Fasiti Arabiki ni Bangladesh, Muhammad Abdur Rashid, sẹ fidi rẹ mulẹ.

Lara awọn ohun tawọn musulumi maa n ṣe ni Hajj ni rinrin yika Kaaba ti wọn maa n pe ni Tawaf nigba meje laarin oke Safa si Marwa.

Eyi ni ṣe pẹlu iriri Hajara nigba ti o n rin ninu igbo fun igba meje ki o to ri omi Zamzam.

Bo tilẹ jẹ pe mimu omi Zamzam ko pọn dandan fawọn to n ṣiṣẹ Hajj, awọn musulumi gbagbọ pe mimu omi naa tọ sunnah gẹgẹ bi ẹkọ ojiṣẹ Ọlọrun Muhammadu.

Ọpọ awọn oṣiṣẹ alalahaji lo maa n mu omi yii lẹyin ti wọn ba ti yika Kaaba tan.

Ileeṣẹ to n wa ohun alumọni inu ilẹ ni Saudi lo n ṣagbatẹru omi Zamzam yii.

Oríṣun àwòrán, AFP

Bawo ni omi Zanzam yii ṣe maa de awọn orilẹede mii?

Bo tilẹ jẹ pe wọn maa n gba awọn to lọ Hajj laye lati bu omi Zamzam lọ ile, awọn alaṣẹ orilẹede Saudi ti ṣe ikilọ pe ẹnikẹni ko gbodọ ta omi naa.

Amọ, ẹri wa pe awọn kan ti gbiyanju lati ta omi Zamzam ri lorilẹede UK.

Ninu oṣu Karun un, ọdun 2011, ileeṣẹ iroyin BBC ṣafihan omi kan ti wọn pe ni omi Zamzam ninu ogo to wa ninu ṣọọbu fun tita ni UK.

Eyi lo jẹ ki awọn alaṣẹ ijọba Saudi Arabia kan nipa pe ẹnikẹni ko gbọdọ ta omi Zamzam mọ.

Ileeṣẹ to n wa ohun alumọni inu ilẹ ni Saudi lo n ṣagbatẹru omi Zamzam yii.

Lati inu kanga ni wọn ti n gbe omi yii kója ninu egboro lọ si ibi ti ẹrọ yoo ti fọ omi naa mọ.

Lati ibẹ ni awọn ọkọ tanka ti n lọ gbe omi yii lọ fun ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan lojoojumọ ati lọ si ile itọju omi nla ti wọn fi orukọ Ọba Abdulaziz Sabeel sọ ni Madinah.

Lati ibẹ lawọn olujọsin ti n ri omi yii lo ni mọṣalaaṣi nla ojiṣẹ Ọlọrun.