Wo ohun márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwòrán Ààrẹ Tinubu ‘tó jẹ́ fọ́tò tó tóbi jùlọ lágbàáyé’

Aworan Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Google

Patako nla kan ti aworan Aarẹ Bola Tinubu wa lara rẹ, ni okunrin ayaworan to yaa ti salaye wi pe idi ti oun fi sagbejade iṣẹ ọun ni lati fi bu iyi kun idagbasoke omọniyan nipase iṣẹ ọna ṣiṣe.

Olaore Opeyemi tii ṣe ayaworan naa sọ fun BBC pe oun jẹ ọkan lara awọn ayaworan to gbero lati safihan iṣẹ naa faraye ri.

Nidi ati ṣatileyin fun ijọba lasiko ti nnkan ko fi bẹẹ sẹnu re lẹka eto ọrọ aje ilẹ Naijiria.

Igbesẹ ṣiṣi aṣọ loju eegun aworan nla ti Aarẹ Bola Tinubu naa, lo wa lara awọn eto ti wọn fun isaami ayẹyẹ ayajọ ọdun marundinlọgbọn ijọba awarawa ilẹ Naijiria to waye ni ọjọ kejila Osu kẹfa.

Ayẹyẹ naa lo waye ni papa Eagle Square to wa ni ilu Abuja l’Ọjọru ọsẹ yi.

Lati igba ti iṣejọba ologun ti pari lọdun 1999, Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun-un ni wọn fi n saamin ayẹyẹ ijọba tiwa n tiwa, ko to ọdun 2018 ti Aarẹ ana Muhammadu Buhari paarọ rẹ si ọjọ kejila oṣu kẹfa.

Ayajọ ọjọ kejila oṣu kẹfa naa, lo wa fun iranti Moshood Kashimawo Olawale Abiola ti ọpọ mọ si MKO Abiola, ti wọn sọ pe o jawe olubori nibi eto idibo Aarẹ ti June 12 Ọdun 1993.

Ohun ti awọn eeyan n sọ ni wi pe aworan nla Aarẹ Tinubu ọhun lo jẹ eyi to tobi julọ lagbaye sugbọn ajọ World Guiness Record gbọdọ kọkọ fidi rẹ mulẹ bẹẹ.

Ninu aworan nla naa, ni Aarẹ Tinubu ti wọ aṣọ agbada funfun, fila idamọ rẹ, pẹlu ilẹkẹ lọrun ati lọwọ rẹ.

Gẹgẹ bi Opeyemi tọ je ọkan lara awọn to ya aworan naa ṣe sọ, iwọn giga patako naa lo to iwọn ẹsẹ bate 32 si 64.

Nibayi naa, akọsilẹ ti ajọ World Guiness Record ni lo n sọ nipa aworan to wuyi julọ lagbaye, ṣugbọn ti Olaore sọ pe o yato gbedengbe si iṣẹ aworan ti won ṣẹṣẹ gbe jade naa.

Lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹfa Ọdun 2019, ni wọn ṣe agbekale aworan nla kan ti giga rẹ to iwọn ẹsẹ bata 130,0991 latọwọ Hung Chi-Sung ni orilẹ ede China.

Alaye ree nipa patako aworan nla naa

  • Oṣu mẹjọ lo gba awọn to ya aworan naa ki wọn to pari rẹ.
  • Jinadu Toyin
  • Adele Oladipupo
  • Olaore Opeyemi

Gẹgẹbi Olaore ṣe sọ, o ni Jinadu Toyin tii ṣe alakoso ibudo ayaworan ti wọn ti ya patako aworan nla naa lo jẹ adari wọn.

O ni oun jẹ ọkan lata ọmọ ẹgbẹ oniṣẹ ọna ati aṣa nilẹ Naijiria.

Olaore salaye fun BBC pe awọn mẹta loni iṣẹ naa, ṣugbọn oun san owo fun awọn meji yooku lati kun oun lọwọ lati ṣagbejade rẹ.

  • Awọn ayaworan mẹtadinlogoji lo parapọ ṣiṣẹ naa.
  • Iwọn fifẹ rẹ to iwọn ẹsẹ bata 32 si 64.
  • Olaore sọ pe, Ibudo igbafẹ lo yẹ fun ririmọlẹ rẹ wa nitori bo ti fẹ to.
  • Ajọ World Guiness Record ko tii gbe ọrọ aworan ọhun wọ inu iwe akọsilẹ wọn nipa bi wọn ko tii ṣe ni iru rẹ nibẹ ri.

Olaore tọka sii pe wọn ti lọ forukọ sile fun aworan naa, ṣugbọn wọn ko tii bawọn luu lontẹ.