Wo òfin tí ìjọba Tinubu fẹ́ gbé kalẹ̀ lórí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tó ń sun ilé ìtura ní Nàìjíríà

Aworan ọdọbinrin

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Minisita fun ọrọ awọn obinrin lorilẹede Naijiria, Uju Ohaneye ti sọ pe ijọba apapọ ko ni fi aye gba awọn ọdọ ọmọbìnrin tí ko ti balaga lati ma sun ni ile ìtura kaakiri orilẹede Naijiria mọ.

O ni igbesẹ yii da lori igbiyanju ìjọba apapọ lati gbe ogun ti owo tarakata awọn ọdọ ọmọbìnrin to wọpọ bayii.

O sọ eyi ni bi apero kan ti oludamọran si Aarẹ Bola Tinubu lori eto ẹkọ, Abiola Arogundade gbe kalẹ.

Ohaneye tẹsiwaju pe yatọ si fifi ofin de awọn ọdọ ọmọbìnrin lati ma sun sí ile ìtura mọ, ẹka ìjọba to n ri si ọrọ awọn obinrin ti gbe igbesẹ lati fopin si iku ojiji nítorí awọn ile iwosan ko ni ni anfani lati ni awọn ko ni tẹwọgba alaarẹ to nilo itọju kiakia mọ.

“Iya n jẹ awọn obinrin lorilẹede Naijiria. Lonii, a ti sọrọ lori bi awọn mẹkunnu yoo se ri imu mi lorilẹede Naijiria.

“Ẹwẹ, mo rí fọnran to ja kiri nípa àwọn ọdọ ọmọbìnrin tí wọn gbe lọ Ghana. Ṣe ẹ ti rí?

“Igbesẹ yoo bẹrẹ lọjọ Aje. Ẹ yoo gbọ nípa igbesẹ wa lọjọ Aje. Ohun ni nnkan akọkọ tí mo maa gbajumọ, ti a yoo si wa nnkan ṣe sí.

“Naijiria gbọdọ dara. Lati ogunjọ oṣu kẹfa, a ti pàṣẹ fun awọn ile ìtura làti gbe patako síta pe awọn ọdọ ọmọbìnrin ko le wa ni ile ìtura.

“Nnkan to waye nípinlẹ Niger ko gbọdọ waye niluu Abuja.

“Bakan naa awon ile iwosan yoo maa se itọju awọn eeyan to nilo itọju kiakia. Eyi ni awọn ìṣòro ti a ni lorilẹede Naijiria.”