Wo ìdí tó ṣe pọn dandan fún obìnrin láti ṣègbéyàwó ọlọ́pọ̀ èrò ní ìlú Shao

Àwọn ìyàwó

Iyawo dun lọsingin, ọkọ tun mi mi gbe.

Aṣa igbeyawo jọ ohun pataki nilẹ Yoruba eyi ti wọn kii fi ọwọ yẹpẹrẹ mu rara.

Bi eto igbeyawo si ṣe maa n waye yatọ ni ileto si ileto ati ilu si ilu.

Eyi lo gbe wa gunlẹ si ilu Shao, ni ijọba ibilẹ Moro ni ipinlẹ Kwara lati tọpinpin aṣa eto igbeyawo to maa n waye nibẹ.

Ni ilu Shao, ẹẹkan lọdun ni ayẹyẹ igbeyawo maa n waye, ni eyi ti wọn maa n ṣe lasiko ti wọn ba n ṣe ọdun Awọnga.

Ohun to ya igbeyawo yii yatọ si ti ayẹyẹ igbeyawo nilẹ Yoruba toku ni pe ọjọ kan ni gbogbo awọn omidan to ba ti to lọ sile ọkọ maa n ṣegbeyawo lati lọ sile ọkọ.

Gẹgẹ bi iwadii wa ṣe fi fidi rẹ mulẹ, wọn ni laye igba kan, koo si bi eniyan ṣe le ni owo tabi ọla to, dandan ni fun wọn lati kopa nibi ayẹyẹ ọlọpọ ero to o ba ti jẹ ọmọ bibi ilu Shao.

Bawo ni ọdun Awọnga ṣe bẹrẹ?

ÀWỌN ÌYÀWÓ

Ọdun Awonga jẹ ọdun to ti wa lati gba iwasẹ to si ni itumo kikun si awọn eniyan ilu Shao.

Gẹgẹ bi itan, ọdun yii bẹrẹ pẹlu obinrin kan ti orukọ rẹ njẹ Awọn, ti o gba ọna ara yọ si ọdẹ kan ti wọn n pe ni, Omo Olarele.

O si sọ fun un pe oun ni o ni odo ti ọdẹ naa ti ma n mu omi ni gbogbo igba to ba lọ sọdẹ.

Awọn jẹ obìnrin ọlọmu kan, o si beere fun ohun kan pere lọwọ ọdẹ naa.

O ni ki o gbe oun lọ si aafin Ọhọrọ iluu Shao akọkọ, Oba Olanibo, o si gba sii lẹnu.

Lẹyin ọpọlọpọ ipade ti Awon se pẹlu Ọhọrọ ati awon ijoye rẹ, o poora pada.

Sugbọn ki o to lọ, o fun wọn ni oogun kan, o si pa a lasẹ wi pe ki wọn sọ ilu naa ni orukọ oun.

Bakan naa, o ni ki wọn ya ọjọ kan sọtọ ninu ọdun fun iranti oun ati lati se igbeyawo fun gbogbo awon ọmọ obinrin to ti to ile ọkọ lọ ni ọjọ kan naa.

Itan tun fi kun un pe, Awon ṣe ileri ibukun fun gbogbo ọmọ ilu ati alejo ti wọn ba tẹle awon ilanaa rẹ.

O sọ wi pe ki wọn maa beere ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ ni igbakuugba, papaa julọ, bi ọjọ bayii ti wọn se ọdun Awon.

Lati igba naa ni fífi awọn ọmọbìnrin fun ọkọ lọjọ Ọdun Awonga o si ti di etutu ati ara asa ati ise iluu Shao, ti wọn si n pe ilu naa ni Shao Awonga

Ki ni yoo ṣẹlẹ si ọmọbinrin ti ko ba kopa nibi igbeyawo ọlọpọ ero Shao?

Oba Etutu ilu Shao, Ọjọgbon Mobalaji Ajakitipa sọ pataki ṣiṣe ọdun Awonga ati ohun ti o ṣeeṣe ko ṣẹlẹ ti wọn ba kọ lati ṣe ọdun naa.

Ajakitipa sọ fun BBC News Yoruba pe ọdun naa ṣe pataki pupọ nitori ohun gan-an ni ipilẹ to gbe ilu Shao ro.

“Ohun gbogbo ti a ba ti pe ni ipilẹ, o se pataki nítorí pe ipilẹ ni idajọ Eledumare.

“Laaarin Awọn ati awọn agbagba ilu Shao nigba ti ẹbọra naa ba wọn lalejo, ipilẹ wọn ni pe, wọn gbọdọ maa ṣe gẹgẹ bi ohun ti fẹ, ki idunnu ati ayọ ti wọn n tọrọ le maa wa ninu ilu.”

Ogbantarigi oniṣẹṣe naa ni awọn n mu ileri ti wọn ti ṣe fun Awọn ṣe lati ipilẹ ki iṣẹlẹ buburu ma ba a ṣẹlẹ si awọn ọmọ ilu Shao, ki ogun si ma ja awọn.

“Idi niyii to fi pọn dandan ki a fa ọmọ fọkọ ninu ilu ni ọdọọdun, ti a ba n ṣe eleyii, ko ni jẹ ki ogun wọ ilu, agbara kagbara ko si le raye ninu ilu.

“Awon yoo ma se atilẹyin gẹgẹ bi o ti seleri rẹ fun wa, ohun gbogbo yoo si maa tuba, yoo ma tusẹ ti a o ba pada nibẹ.”

O tẹsiwaju pe awon baba nla awọn ti ṣeto naa kalẹ fun wọn ki ifẹ ba le wa ni ilu, ki ayọ awọn si maa lekun ní gbogbo igba.

“Itumo Awọn ni pe a maa n fa ọmọ fun ọkọ nigba nigba, lẹgbẹrun lẹgbẹrun, Iya Awọn jẹ ebọra pataki, to fun wa ni isẹgun nigba ogun, o si fi agbara kun agbara awon alagbara wa.

“Eyi lo faa ti a o fi lee gbagbe rẹ lailai, ta fi n korajọ pọ lati ṣe ajọyọ ati igbeyawo gẹgẹ bi o ti fi lelẹ.”

O fi kun ọrọ rẹ pe ayọ ati ibukun lọpọ yanturu ni ọrọ awọn n jasi latara bi awọn ṣe maa n ṣe ọdun naa ni gbogbo igba ti awọn si n fi ọmọ fọkọ papọ.

Ajakitipa ni igbagbọ wa pe nnkan le ma lọ deede fun awọn ninu ilu Shao ti awọn ba kọ lati tẹsiwaju ninu aṣa naa.

O tẹsiwaju pe ọmọbinrin to ba ti bimọ ni anfani latoi kopa nibi ayẹyẹ yii pe ko pọn dandan ko jẹ pe awọn omidan nikan lo le kopa nibẹ.

“Ohun to ṣe pataki ni pe ki wọn kopa nibi ayẹyẹ igbeyawo ilu.”

Kí ló dé tí àwọn ìyàwó fi maa ń gbé aburẹdà lọ́wọ́ lasiko igbeyawo yii?

ÀWỌN ÌYÀWÓ

Omowe Sangodare Ayinla to jẹ ọmọ ilu Shao ni tan molẹ si idi ti awon tuntun fi maa n gbe aburẹda lọwọ nibi ọdun igbeyawo ọpọ eniyan naa.

Sangodare sọ wi pe, lotitọ, ẹbọra Awọn ko pọn ni dandan fun ilu lati maa se ọdun naa pẹlu aburẹda bẹẹ si ni ko si lara awon ilana ti o fi kalẹ.

O ni nitori pe gbagede ni awon iyawo naa maa n duro si nibi ayẹyẹ naa ni wọn ṣe maa n lo o.

O ṣalaye pe o seese ki oorun mu pupọ ju lasiko ayẹyẹ naa tabi ki ojo ṣadede sọkalẹ, aburẹda yii ni wọn yoo fi daabo bo ara wọn ki oorun tabi ojo ma baa ba ẹsọ ti awọn iyawo ṣe si ara jẹ.

O fi kun pe ko si ohunkohun ti yoo ṣẹlẹ ti wọn ko ba lo aburẹda naa.

Ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2023 ni ayẹyẹ igbeyawo ọlọpọ eero ti ọdun waye ni ilu Shao

Awọn ọmọbinrin mẹrindinlogoji ni wọn fi fọkọ nibi ayẹyẹ igbeyawo Awon lọdun yii.

Ohun ti a ṣe akiyesi ni pe ero ko fi bẹẹ pọ nibi ayẹyẹ igbeyawo ọlọpọ ero yii mọ bii ti igba kan.