Wo ìdí tí Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe, ASUP náà ṣe gùnlé ìyanṣẹ́lódì àìlópin

ASUP

Oríṣun àwòrán, @justeventsonlin

Ẹgbẹ awọn olukọ ile ẹkọ gbogboniṣe, ASUP, ti gunle iyanṣelodi ọlọjọ gbọọrọ lati bere fun atunto bi ijọba ṣe n san owo oṣu wọn.

Gẹgẹ bi ohun ti ẹgbẹ naa sọ, iyanṣelodi ọhun ti bẹrẹ lonii ọjọ Iṣegun, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2021.

ASUP kede iyanṣelodi naa lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba apapọ niluu Abuja.

Yatọ si atunto bi ijọba ṣe maa n san owo wọn ti wọn n bere fun, ASUP tun sọ pe ki ijọba san owo to jẹ awọn olukọ lawọn ile ẹkọ gbogboniṣe lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria.

Wọn tun fi ẹsun kan ijọba pe o kọ lati san owo oṣu mẹwaa to jẹ awọn oṣiṣẹ wọn lẹyin to buwọlu owo oṣu tuntun to kere ju fun awọn oṣiṣẹ.

ASUP

Oríṣun àwòrán, @justeventsonlin

ASUP ni iyanṣelodi ọhun ṣe pataki lasiko yii, paapaa niwọn igba ti ijọba apapọ ti kọ lati mu awọn ileri to ṣe fun awọn ṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Arẹ apapọ ẹgbẹ naa, Anderson Ezeibe ni, bo tilẹ jẹ pe awọn yoo ṣi maa ba ijọba apapọ jiroro, ko si ohun ti yoo da iyanṣelodi ọhun duro ayafi ti ijọba ba da awọn lohun.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ko pẹ ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fasiti, ASUU, wọgile iyanṣẹlodi ti awọn naa gunle lẹyin oṣu mẹsan an gbako.

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ, JUSUN, ati ẹgbẹ awọn dokita naa ti bẹrẹ iyanṣẹlodi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ