Wo ìdí tí báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà CBN fi tilẹ̀kùn mọ́ àwọn tó ń sẹ owó dọ́là, pọ́ùn ní Nàìjíríà

Banki apapọ orilẹede Naijiria ti gbẹsẹle tita awọn owo ilẹ okeere fun awọn olokoowo paṣipaarọ owo ilẹ okeere ti ọpọ mọ si Bureau de Change ni Naijiria.

Godwin Emefiele to jẹ gomina agba banki apaps Naijiria lo kede eyi ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn oniroyin lẹyin ipade igbimọ kokaari lori ilana iṣuna.

O ni iye owo dọla amẹrika ti wọn n ya sọtọ fun awọn olokoowo ṣiṣẹ owo ilẹ okeere naa ko lee yọ mọ.

Emefiele tun ṣalaye pe awọn olokoowo ṣiṣẹ owo ilẹ okeere naa ti sọ ara wọn di ọpa ipọnwo kotọ lorilẹede Naijiria. O ni wọn ti kọ ẹyin si ojuṣe wọn, wọn si ti sọ ara wọn di agbodegba iwa jibiti ati ikowojẹ lorilẹede Naijiria.