Wo bí afurasí ọmọ ọdún 16 àti 17 ṣe pa ọmọ ọdún 11 láti fi ṣe ètùtù ọlà

Awọn ọmọkunrin naa lẹyin ti ọwọ tẹ wọn

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Ghana ti ko ọdọmọkunrin meji to pa ọmọ ọdun mọkanla kan fun etutu ọla, lọ sile ẹjọ.

Ẹsun ti wọn fi wọn fi kan awọn ọdọmọkunrin naa ni pe wọn gbimọpọ lati panioyan.

Ọmọ ọdun mejidinlogun, ati mọkandinlogun ni awọn ọdọ naa, Felix Nyarko ati Nicholas Kini.

Gẹgẹ bi nkan ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ, awọn afurasi naa jẹwọ pe awọn pa ọmọkunrin naa lẹyin ti awọn wo ipolowo babalawo kan lori amohunmaworan.

Lẹyin ti wọn wo ipolowo naa tan, ni wọn pe babalawo naa ‘malam’, to n gbe ni ẹkun Volta.

Oun lo ṣeleri fun wọn pe oun yoo sọ wọn di olowo, ti wọn ba le mu ẹgbẹrun marun-un Cedis owo Ghana, ati oku ẹni ti ko ni ibalopọ ri, wa fun oun.

Idi si re e ti wọn fi n tọpinpin ọmọkunrin , ọmọ ọdun mọkanla naa, Ishmael Mensah, titi wọn fi pa a sinu ile kan ti wọn n kọ lọwọ.

Iroyin sọ pe niṣe ni wọn fi ọgbọn ẹwẹ tan ọmọ ọdun mọkanla naa lọ sinu ile ọhun, ti wọn si fọ bulọọki ikọle mọ lori titi to fi ku.

Ọjọ Satide ni iṣẹlẹ yii waye ni ilu Kasoa, ni nkan bi aago marun-un irọlẹ.

Iyalẹnu ati ibẹru ni iṣẹlẹ naa jẹ fun awọn olugbe agbagbe Kasoa, paapaa nigba ti wọn ri i pe awọn ọdọmọde lo ṣe iru nkan bẹ ẹ.

Ni bayii, awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana ti n pariwo pe ki awọn alaṣẹ fi ofin de ipolowo ọja ti awọn babalawo ma n ṣe ni awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ, amohunmaworan ati awọn mii.