Wo àwọn òṣìṣẹ̀ ìjọba tó ń gba owó ju ààrẹ lọ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà

Aarẹ Buhari n ka iwe

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Bawo ni yoo ṣe ri leti rẹ bi o ba gbọ pe awọn oṣiṣẹ kan wa lẹnu iṣẹ ọba lorilẹede Naijiria ti owo oṣu wọn ju owo oṣu ti aarẹ orilẹede Naijiria gangan n gba lọ?

Ajọ to n risi pinpin owo oṣu fun awọn to dipo oṣelu mu ni Naijiria, RMAFC sọ pe awọn oṣiṣẹ ọba kan n gba owo oṣu to pọ ju ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lọ.

Alaga ajọ RMAFC, Mohammed Shehu lo ṣi aṣọ loju ọrọ yii o lasiko to fi n dahun ibeere kan lori eto amohunmaworan abẹle kan ni Naijiria lọjọbọ.

Shehu sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ ijọba apapọ kan bii ajọ to n ṣe amojuto ati abo oju omi ni Naijiria, NIMASA, Ajọ ibaraẹnisọrọ, NCC, ajọ to n mojuto awọn ebute omi lorilẹede Naijiria, NPA ati Banki apapọ Naijiria CBN wa lara awọn to n gba owo ju aarẹ orilẹede Naijiria lọ lọwọ yii.

Owo oṣu aarẹ ko to miliọnu kan ati ọọdunrun naira loṣu… awọn ajẹmọnu to tọ si aarẹ wa lara owo oṣu naa o. ni ọdun 2018, oju owo gọbọi leeyan yoo fi wo eyii ṣugbọn bayii, awọn oṣiṣẹ wa lẹka aladani ati iṣẹ ọba ti wọn n gba ilọpo meji, ilọpo mẹta, ilọpo mẹrin rẹ.”

Ipele owo oṣu oriṣi mẹtadinlogun lo wa ni Naijiria

Goolu wa niwaju aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Gẹgẹ bi alaga ajọ to n risi pinpin owo oṣu fun awọn to dipo oṣelu mu ni Naijiria, RMAFC Mohammed Shehu ṣe sọ, ipele mẹtadinlogun lo wa ni eto owo oṣu ni Naijiria kaakiri awọn lajọlajọ gbogbo.

O wa woye pe asiko to lati tun eto owo oṣu gbe yẹwo ni awọn iṣẹ ọba ni Naijiria nitori, gẹgẹ bi o ṣe sọ, ko yẹ ki owo oṣu oṣiṣẹ ijọba kankan maa pọ ju ti aarẹ lọ.

Bakan naa lo ni a ri awọn oṣiṣẹ ijọba kọọkan ti owo gba maa binu fun kikuro lẹnu iṣẹ ti wọn n san fun wọn pọ to miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira to si jẹ pe owo to tọ si aarẹ orilẹede Naijiria to ba kuro nipo ko ju miliọnu mẹwaa Naira lọ.

Agbeyẹwo yoo wa lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ

Aarẹ Buhari n juwọ si awọn eeyan kan lasiko abẹwo rẹ si Katsina

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Bakan naa ni Shehu Mohammed tun kede rẹ pe, laipẹ, Agbeyẹwo yoo wa lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ atawọn oṣiṣẹ ọba lati wa ni ibamu pẹlu bi eto ọrọ aje ṣe ri lorilẹede Naijiria lọwọ yii.

O ni awọn ajọ ijọba kan ṣi wa to jẹ pe owo to ṣi wa ni akata wọn ti wọn ko tii da pada si aṣuwọn ijọba le ni tiriliọnu meje naira.

O wa rọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorilẹede Naijiria, EFCC lati fi awọn ileeṣẹ ijọba ati lajọlajọ tọrọ kan jofin.

Bakan naa lo tun rọ ijọba apapọ lati ṣiṣẹ lori abajade iwadi igbimọ Steve Oronsaye ti wọn gbe kalẹ siwaju ijọba ni bi ọdun mẹwaa sẹyin lati pa gbogbo awọn ileeṣẹ ati ajọ ijọba to n ṣe iṣẹ kan naa lọna ọtọọtọ pọ gẹgẹ bi ara ọna lati din ifowo ilu ṣofo ku.