Wo àwọn ode eré tí Davido ti pa tì nínú oṣù Kọ́kànlá yìí látàrí ikú Ifeanyi ọmọ rẹ̀

Davido

Oríṣun àwòrán, @davido

Gbajugbaja olorin takasufee Naijiria, Davido, ti wọgile ọpọ ode to yẹ ko ti lọ kọrin lẹnu ọsẹ diẹ sẹyin lẹyin iku ọmọ rẹ, Ifeanyi.

Lati ibẹrẹ oṣu Kọkanla yii lo ti fi ori ayelujara silẹ, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ ko si ri ni ita gbangba.

Koda, lọjọ to pe ẹni ọgbọn ọdun loke eepẹ, ko sọ nnkankan, bẹẹni awọn ololufẹ rẹ ko gbọ ọrọ kankan lati ọdọ rẹ.

Lọjọ kọkanlelogun to pe ẹni ọgbọn ọdun naa, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ki oriire, ti ọpọ wọn si sọ pe awọn n saaro rẹ.

Ṣaaju iku ọmọ rẹ ni Davido ti kọkọ sọ pe oṣu Kọkanla ọdun yii maa yatọ, nitori inu oṣu naa ni yoo pe ẹni ọgbọn ọdun.

O sọ pe oun ti ni awọn alakalẹ eto fun inu oṣu naa gẹgẹ bii atẹjade to fi lede loju opo Twitter rẹ.

Lara awọn eto ti Davido ti pati ree lẹyin iku ọmọ rẹ;

Are We African Yet (A.W.A.Y)

Ilu Atlanta, Georgia lo yẹ ki eto A.W.A.Y yii ti waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla ti a wayii nilẹ Amẹrika.

Lara awọn olorin to yẹ ko ṣere nibẹ ni Kizz Daniel, Oxlade, Adekunle Gold, atawọn mii.

Ọjọ kan lẹyin  ọjọ to yẹ ki eto naa waye ni awọn to n ṣagbatẹru re kede pe awọn ti sun siwaju pẹlu ọdun kan ki Davido le ri aye kẹdun pẹlu awọn ẹbi rẹ.

Puma x Davido Collabo

Oṣu Kejila ọdun 2021 ni iroyin gbode pe Davido ti tọwọ bọwe adehun pe ileeṣẹ Puma lati jẹ oju ileeṣe naa.

Lati inu oṣu Kẹwaa ọdun yii si ni Davido ti n sọrọ lori ibaṣepọ rẹ ati ileeṣẹ ọhun.

Amọ ileeṣẹ naa ti wa kede pe awọn bata tuntun ti wọn fẹ gbe jade ni ibaṣepọ pẹlu Davido ni ko ni waye mọ lasiko yii, awọn si ti ṣetan lati da owo awọn eeyan to ti san owo awọn bata naa ṣaaju pada.

Ayẹyẹ ọjọ ibi Davido

Awọn ololufẹ Davido ko gbọ nnkankan lati ọdọ rẹ lọjọ ibi rẹ to pe ọgbọn ọdun laye.

Iroyin ni o ti n mura lati ṣe ajọyọ nla fun ọjọ ibi naa ṣaaju iku ọmọ rẹ.

Lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọdun to kọja lo ke si awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn fi owo ṣọwọ si oun lati gbe ọkọ bọgini kan wọ Naijiria, ninu eyii ti awọn araalu ti fi nnkan bii igba miliọnu naira sọwọ si, amọ awọn ọmọ alailobi lo fun ni owo naa ni ikẹyin.

Iburawọle gomina tuntun ni ipinlẹ Osun

Ni bayii to ku ọjọ perete ti wọn yo burawọle fun ẹgbọn Davido, Ademola Adeleke gẹgẹ bii gomina tuntun ni ipinlẹ Osun, ko si ẹni to tii le sọ boya Davido yoo yọju ibi iburawọle naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Davido wa lara awọn mọlẹbi gomina tuntun naa to gbe ipolongo ibo rẹ lori.

Davido sọ fun BBC lẹyin eto idibo naa niluu Ede pe oun n ṣatilẹyin fun ẹgbọn oun nitori ẹbi ṣe pataki si oun gidi.