Wo agbègbè mẹ́fà tí òòrùn kìí ti wọ̀ fún àádọ́rin ọjọ́ nílé ayé

Oorun to yọ

Oríṣun àwòrán, Andrew Fusek Peters

Igbe aye gbogbo ẹda lo wa yika wakati mẹrinlelogun tii se odidi ọjọ kan, wakati mejila fun ọsan ati wakati mejila fun oru.

Amọ bawo ni aye ẹda kan yoo ti ri, ti oorun ko ba pa oju de fun ọjọ gbọọrọ, bawo ni wọn se fẹ mọ ọṣan yatọ si oru?

Bawo ni awọn arinrin ajo afẹ yoo ti se ni ibudo kan ti oorun ko ba wọ nibẹ fun aadọrin ọjọ leralera?

Koda iye onka ọjọ gan ko ye awọn araalu gan to wa ni awọn irufẹ ibudo bẹẹ mọ nigba ti oorun ko wọ mọ rara?

Awọn agbegbe mẹfa ree yika agbaye nibi ti oorun kii ti wọ rara, gbogbo akoko ọsan ni nibẹ laisi oru.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ibudo mẹfa ni agbaye ti oorun kii ti wọ:

Orilẹede Norway:

Ni orilẹede Norway, ni agbegbe ti aye ti yipo, (Norway, in the Arctic Circle) ni wọn n pe ni “Ilẹ ti oorun ti n jade loru”.

Lati osu karun ọdun, eyiun May titi di ipari osu keje July, oorun kii wọ ni agbegbe yii rara fun ọjọ mẹrindinlọgọrin

Ni agbegbe Svalbard lorilẹede Norway, oorun maa n ran lati ọjọ Kẹwa osu Kẹrin April titi wọ ọjọ Kẹtalelogun osu Kẹjọ August ni.

Ẹyin naa le seto lati se abẹwo si agbegbe yii lawọn akoko ta mẹnuba naa , kẹ si duro fun ọjọ pipẹ lai foju kan okunkun tabi oru.

Agbegbe Nunavut ni orilẹede Canada:

Oorun to yọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbegbe Nunavut to wa ni orilẹede Canada naa sunmọ agbegbe ti aye ti yipo (Arctic Circle)ni awọn apa iwọ oorun ariwa orilẹede Canada.

Agbegbe yii maa n ri oorun ni ojoojumọ fun osu meji gbako, amọ nigba to ba di akoko otutu, inu okunkun biri biri ni agbegbe naa maa n wa fun ọgbọnjọ, tii se osu kan gbako.

Eyi tumọ si pe oorun kii ran rara lawọn akoko ti otutu ba mu lagbegbe naa.

Orilẹede Iceland:

Orilẹede Iceland lo jẹ erekusu to tobi julọ ni ilẹ Yuroopu lẹyin United Kingdom, bakan naa lo jẹ orilẹede ti ẹfọn ẹyọ kan soso ko si nibẹ rara.

Lasiko ooru, ko si okunkun rara ni orilẹede Iceland , to ba si ti di osu Kẹfa June, oorun kii wọ nibẹ rara.

Tẹ ba fẹ mọ bi ọsan ati oru bi Ọlọrun se da wọn, ẹ le se abẹwo si erekusi Akureyri ati Grimsey to wa ni agbegbe ti aye ti yipo.

Agbegbe Barrow ni Alaska lorilẹede Amẹrika:

Oorun to yọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati ipari osu Karun May titi wọ ipari osu Keje July, oorun kii wọ ni agbegbe Barro to wa nipinlẹ Alaska ni orilẹede Amẹrika.

Amọ to ba di ibẹrẹ osu Kọkanla November, ọgbọnjọ pere ni oorun fi maa n yọ, eyi si ni wọn n pe ni ‘polar night’.

Itumọ rẹ ni pe ilẹ naa yoo wa ninu okunkun lasiko ti otutu ba mu, ti oorun ko si ni yọ nibẹ mọ.

Bakan naa ni agbegbe yii gbajumọ fun awọn yinyin to ti di oke, o si dara lati se abẹwo si agbegbe yii lasiko ooru tabi otutu.

Orilẹede Finland:

Orilẹede Finland jẹ ilẹ to kun fun ẹgbẹlẹgbẹ adagun odo ati erekusu .

Ọpọ agbegbe to wa ni orilẹede Finland lo n ri oorun taarata fun ọjọ mẹtalelaadọrin gbako lasiko ti ooru ba mu.

Amọ lasiko otutu, ko ni si oorun rara, ti ko si nmi yọ rara.

Idi ree ti awọn eeyan orilẹede Finland kii se sun pupọ lasiko ooru ati ni asiko otutu.

Ti ẹ ba wa ni agbegbe yii, ẹ ni anfaani lati ri ‘ina ila oorun’ ina to mọlẹ rokoso, ti eeyan si tun le sere idaraya sisare lori yinyin.

Orilẹede Sweden:

Lati ibẹrẹ osu Karun May si ipari osu kẹjọ August, ni orilẹede Sweden ti maa n foju kan oorun ti yoo yọ lati aago mẹwa aarọ, ti ko si ni wọ mọ.

Tẹ ba lọ sibẹ, ẹ le lo akoko yin lati maa fi se ere idaraya Golf, pa ẹja ninu odo tabi rinrin ajo afẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: