Wo àǹfàní tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ fún ìyàwó Sunday Igboho ní Cotonou

Iyawo Sunday Igboho

Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ti ṣalaye bi nkan ṣe n lọ lori igbẹjọ Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye fi sita ni o ti ṣalaye pe awọn ẹṣọ eleto abo ti yọ ṣẹkẹ-ṣẹkẹ kuro lọwọ Igboho bayii.

Wọn ni alẹ ọjọ Abamẹta ni awọn ẹṣọ yọ ma mun gaari kuro lọwọ Igboho.

Ni bayii, wọn ti fun iyawo Igboho, Ropo ni anfaani lati ri ọkọ rẹ ni igba mẹta lojumọ.

Bakan naa, awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti ẹgbẹ Ilana Omo Oodua fi ranṣẹ si orilẹede Benin ti ṣe ayẹwo ilera rẹ.

Ilana Omo Oodua tun sọ pe Igboho ko ṣẹ si ofin irina lati orilẹede kan si omiran rara lorilẹede Benin.

Oni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje ni igbẹjọ Igboho yoo tẹsiwaju, o si ṣeeṣe ki ileẹjọ ṣe agbeyẹwo bo ya ki ijọba Benin da a pada si Naijiria.

Ilana Omo Oodua tun rọ awọn ololufẹ Igboho lati ma ṣe lọ si ile ẹjọ ni Benin.

Wọn rọ wọn wi pe ki wọn duro ni Naijiria ki wọn si maa gbadura fun Igboho.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ni o dawọn loju pe Igboho yoo gba ominira lonii nile ẹjọ.