Wá mọ̀ nípa ẹni tó fẹ Kaaba lójú kẹkẹ sí i láì gba owó

Aworan Kaaba ni Mecca

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣẹ akanṣe to tobi ni ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Muhammad Kamal Ismail gbe kọ ara rẹ lọrun nipa bo ṣe muki Moṣalashi nla ti Haram to wa ni ilu Saudi Arabia tubọ fẹju kẹkẹ sii.

Ọdun 1908 ni wọn bi Ismail ni ilu Egypt, ẹni ti Ọba Fahd ti ilu saudi Arabia to doloogbe fa kalẹ lati lewaju iṣẹ akanṣe fifẹ mọṣalaṣi kaaba ti Mecca ati mọṣalaṣi ti Anọbi to wa ni Medina ko lee tobi daada le lọwọ.

Iṣẹ naa ni wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi to fẹju kẹkẹ julọ ti wọn ṣe ri ni mọṣalaṣi naa lọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Ismail kọ lati gba kọbọ pẹlu gbogbo akitiyan ti Ọba Fahd ati ile iṣẹ abanikole ti Bin Laden sa lati fun un ni owo lori iṣẹ naa.

“Bawo ni maa ṣe gba owo fun ṣiṣe iṣẹ atunṣe Mọṣalaṣi mimọ,

Kini maa sọ fun Ọlọrun lọjọ agbende alukiaomọ? Ismail sọrọ.

Nipa eto ẹkọ ati idile rẹ

Ismail ni akọsilẹ to dara nipa ji jẹ akẹẹkọ to kere julọ lọjọ ori ti yoo wọ ile ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa imọ ẹrọ to wa ni ilu Eygpt to si kẹkọ jade nibẹ.

Awọn orilẹ ede ilẹ Europe ni wọn ran an lọ si lati lọ ni imọ kikun nipa ẹsin islam nigba naa.

Ismail pe ẹni ọdun mẹrinlelogoji ko to ṣe igbeyawo, ti iyawo rẹ si bi ọmọkunrinkan fun un ko to jẹ Ọlọrun nipe.

Lẹyin naa, O mu sisin ọlọrun lọkunkundun, ko to di pe ọlọjọ de si i lẹni ọgọrun ọdun, bakan naa lo tun fi ara rẹ pamọ fun awọn oniroyin lati ma jẹ ki wọn mọ nipa rẹ.

Okuta funfun

Aworan awọn eeyan ni Mecca.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ismail ni ẹni ti daba ki wọn fi okuta funfun ṣe mọṣalaṣi kaaba lọsọ ko lee mu adinku ba iwọn ooru gbigbona ni ilu Saudi Arabia.

Ilẹ Greece ni wọn ti ṣawari irufẹ okuta naa, pẹlu bi ti ṣowọn to.

Okuta funfun ọun jẹ eyi to wuyi loju, bẹẹ lo si ṣeranwọ fun mimu adinku ba ooru gbigbona ninu Kaaba naa, leyi to jẹ mọṣalaṣi to tobi julọ ninu ẹsin Islam.

Nipasẹ alakalẹ itan ni wọn fi fẹ mọṣalaṣi ọun loju kẹkẹ si i, ko lee gba ọgọọrọ awọn olujọsin lasiko awẹ Ramadan, Hajj tabi Umrah leyi ti ẹgbẹlẹgbẹ kan eeyan lee wa ninu rẹ lẹẹkan ṣoṣo.