Wọ́n bá òkú ọmọdébìnrin ọdún 16 nínú wardrobe ilé ìtura

Ile itura naa re e nijọba ibilẹ brass, nibi ti wọn ti ba oku Nengi

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Bayelsa ti bẹrẹ iwadii lori bi ọmọdebinrin kan ṣe ku si ile itura kan niluu Twon, nijọba ibilẹ Brass nipinlẹ naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa, SP Butswat Asinim sọ fun BBC pe wọn ti gbe oku ọmọbinrin naa lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa ni Brass lati ṣe ayẹwo nkan to ṣeku pa a .

Iroyin sọ pe agbálẹ̀ to wọ inu yaara kan nile itura naa lati tun-un ṣe lọjọ̀ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, lo ri oku ọmọdebinrin naa, Nengi Enenimiete, to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun.

Ọjọ Satide ni ọmọbinrin naa ati alejo kan jọ gba yaara si ile itura ọhun, amọ ẹni ti wọn jọ wa ninu yaara da kọkọrọ pada to si kuro nibẹ ni ogunjọ oṣu Kọkanla, to jẹ ọjọ keji.

Inu apoti aṣọ ara ogiri (wardrobe) si ni wọn ti ba oku Nengi Enenimiete, to si ti n run.

Amọ ko si àpá kankan lara rẹ, tabi pe wọn yọ ẹya ara rẹ kankan, tabi fun ni ọrùn pa.

Bi wọn ṣe ri oku Nengi Enenimiete

Ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ ni, bi agbalẹ to ri oku ọmọdebinrin naa ṣe n tun yaara ṣe fun alejo tuntun, lo kiyesi pe omi n ṣan jade lati ibi kan ninu yaara.

Bakan naa ni oorun buruku n jade, eyi to mu ki wọn o ṣe ayẹwo gbogbo yaara naa, ti wọn si ba oku rẹ ninu apoti aṣọ.

SP Asinim Butswat sọ pe oludari ile itura naa tin ṣiṣẹ pẹlu awọn ọlọpaa lati mọ ẹni ti oun ati ọmọbinrin naa jọ gba yaara, ki wọn to ri oku rẹ.

Ọjọ ti pẹ ti wọn ti n ri oku awọn obinrin nile itura ni Port Harcourt

Ni bi ọdun mẹta sẹyin, lọdun 2019, ni wọn bẹrẹ si ni ri oku awọn ọmọdebinrin ni awọn ile itura nilu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers.

Awọn iṣẹlẹ naa mu ki awọn obinrin niluu Port Harcourt, ṣe iwọde lati sọ fun ijọba ati awọn ọlọpaa pe ki wọn o ṣawari awọn to n pa wọn.

Ko din ni ogun ọmọdebinrin mẹsan-an ti awọn ọlọpaa ri ni awọn ile itura niluu naa.

Nkan to wọpọ pẹlu iku wọn ni pe wọn fun wọn ni ọrun pa ni, ti wọn si tun fi okun di ọwọ ati ẹsẹ wọn.

Pẹlu iranlọwọ ẹrọ ayaworan CCTV, ni ọkan lara awọn ile itura ti wọn ti ba oku ọmọbinrin kan, ni ọwọ fi tẹ ọkunrin kan, Gracious David-West, to wa nidi awọn iṣẹlẹ naa.

Ni ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 si ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Rivers, to wa niluu Port Harcourt, da ẹjọ iku fun David-West.

Lọwọlọwọ, ọkunrin naa ṣi wa ni ọgba ẹwọn nla Port Harcourt, nibi to ti n duro de ọjọ iku.