Torí ìjèrè ọkàn ni mo ṣe pe Portable àti Pasuma sí àṣálẹ́ ankara – Oluṣọ ijọ Celestial

Aworan Oluṣọ ijọ Sẹlẹ to pe Portable ati iwe ipe rẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/C.C.C Land Of Goshen Cathedral/Celestial Reality Check

Ọpọ awọn eeyan ni wọn bẹrẹ si nii beere idi ti ijọ Ọlọrun yoo ṣe pe olorin takasufe ati onifuji ti kii ṣe ọmọlẹyin Kristi lati waa kọ orin ninu ile ijọsin.

Ọrọ yii lo ti n tan kalẹ lori ẹrọ ayelujara lati igba ti iwe ipe kan ti jade lori ayelujara pe ijọ Celestial kan, Land of Goshen, pe olorin fuji taa mọ si Alhaji Wasiu Alabi Pasuma ati olorin takasufe, Habeeb Olalomi Portable si aṣalẹ orin iyinlogo ati ankara ti yoo waye nile ijọsin naa.

Oluṣọ ijọ naa lo ti waa jade lati sọ idi to fi gbe iru igbesẹ yii lai wo ohun ti awọn eniyan yoo sọ.

Ninu fọnran kan loju opo ayelujara Facebook, oluṣọ ijọ Land of Goshen, Aderemi Dabiri, fesi si ibeere ti igbimọ ti ijọ Celestial gbe dide lori ọrọ naa bii nipa idi to fi pe awọn olorin to pe.

Dabiri, ninu alaye rẹ wi pe eyi kii ṣe igba akọkọ ti oun yoo pe olorin aye lati waa bawọn jọsin ninu ijọ naa.

Oluṣọ naa ni “pupọ lara awọn ọmọ ijọ wa lo ti di ọmọ ijọ alaṣọ ara ti wọn si ti ṣako lọ, to si jẹ pe oriṣiriṣi ọna ni wọn fi n ko wọn lọ.

“Mo waa joko pẹlu awọn igbimọ mi lati wo ohun taa le ṣe lati gba awọn eeyan yii pada sinu agbo wa. Eyi kii ṣe igba akọkọ ti a maa ṣe iru nkan bayi, ko si bajẹ ri.

Igba akọkọ kọ niyi ti a n pe awọn olorin ti kii ṣe akọrin ẹmi

Oluṣọ ij Sẹlẹ naa tun ṣalaye pe kii ṣe igba akọkọ niyi ti awọn n pe awọn olorin ti kii ṣe akọrin ẹmi wa si ijọ naa.

O ni ọpọ ọkan ni wọn jere sinu agbo ijọ Ọlọrun nipasẹ wọn.

“Bii apẹẹrẹ, nigba taa pe Saint Janet, ọmọbinrin kan n kọja lọ to ni oun fẹẹ lọ para oun ni. Orin to gbọ lo jẹ ko wọle wa ti igbe aye rẹ si yi pada.

“Ko rọrun fun mi lati maa lọ ile ọti abi ibudokọ lati maa waasu ihinrere tori pe ọpọ igba ni wọn ti na wa nibi taa ti lọ waasu.

“Awọn ọmọ kan wa nita to jẹ pe gbogbo iwa ti ko daa lo wa lọwọ wọn, amọ ti aye wọn yoo yi pada ti wọn ba wọ inu ijọ yii wa latara awọn olorin taa maa n pe.

o fi kun un pe pupọ ninu awọn olorin ẹmi ti aye n pariwo wọn lati pe wa sinu ijọ yii ti awọn naa ti waa ṣe iṣẹ iranṣẹ wọn ṣugbọn awọn olorin ti ọpọ n ọọrọ sii yii naa ni wọn ni awọn ololufẹ tiwn ti yoo tori wọn wa sinu ile ijọsin lọjọ ti wn ba wa.

Ṣọ́ọ̀ṣì Sẹ̀lẹ́ pe Pasuma ati Portable láti kọrin láṣàlẹ́ ìyìn, ariwo sọ

Ankara/Iyin night

Oríṣun àwòrán, @Facebook

Latigba ti iwe ipe to n kede Aṣalẹ Ankara ati Iyin lati ẹka Ṣọọṣi Sẹlẹ kan ti jade, nibi ti wọn ti pe olorin Fuji, Alabi Pasuma ati gbajumọ olorin takasufee, Habib Okikiola ti ọpọ mọ si Portable Ọmọ Ọlalọmi lati waa kọrin lawọn eeyan ti n sọ oriṣiiriṣii ọrọ nipa ṣọọṣi naa.

Ọjọru, ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni iwe ipe to n kede Aṣalẹ iyin naa jade sori ẹka ayelujara Facebook.

Ẹka ijọ Mimọ to pe Pasuma ati Portable naa ni wọn pe orukọ ẹ ni Land Of Goshen Cathedral.

Yatọ si Pasuma ati Portable ti wọn jẹ olorin aye, awọn eleto naa tun pe ọmọbinrin olorin kan torukọ rẹ n jẹ May-Shua.

Ẹfanjẹliisi Sunday JP, tawọn eeyan tun mọ si De Governor, (Eebudọla 1 of Lagos) ni pasitọ to han ninu iwe ipe ọhun.

Ero araalu ṣọtọọtọ: Awọn kan ni ibarẹ-aye leyi, awọn mi-in ni o lọ ‘far’

Oriṣiiriṣii ero lo n jade loju opo Facebook lori igbẹsẹ ṣọọṣi yii, bawọn kan ṣe n tabuku rẹ lawọn kan ṣe n sọ pe awọn yoo de ṣọọṣi naa lọọ ṣe faaji.

Wọn ni o lọ ‘far’ gan-an.

Ẹnikan to pe ara rẹ ni Ayọ Ifẹ loju opo naa kọ ọ sibẹ pe, ‘’Awọn olorin tẹ ẹ pe yii ko ti i pe o, ẹ o ba kuku fi Naira Marley naa kun un kẹ ẹ le jere ọkan daadaa’’

Bọlanle Bamidele Adewuyi kọ ti ẹ pe, ‘’Eyi baayan lọkan jẹ pupọ. Ṣe ohun tẹ ẹ sọ ileejọsin Ọlọrun da ree?”

Bakan naa ni Edafe Oghenebrume, sọ loju opo naa pe “Eewọ lohun tẹ ẹ ṣe yii ninu ijọ Sẹlẹ. O ba ni lọkan jẹ, o burui jai, nnkan itiju si ni pẹlu. Emi o mọ iru ẹkọ ti Oluṣọ ijọ yii ni pẹlu awọn ọmọ ijọ rẹ gan-an’’

Ṣugbọn ni tawọn eeyan ti wọn fẹran faaji orin Fuji ati ti Portable, wọn lawọn yoo fẹsẹ kan de ibi ayẹyẹ naa, awọn yoo ṣe faaji rẹpẹtẹ.

Ọmọbinrin kan to pe ara ẹ ni Abikẹ kọ ọ pe, ‘’ Dandan ni ki n wa nibẹ.”

Bẹẹ lẹnikan naa toun n jẹ Abikẹ Garment kọ ọ pe “Emi maa lọ sibẹ o, ki n lọ fijo gbọn ibanujẹ mi danu.”