Tinubu: Buhari ti ṣí ọ̀nà oríire sílẹ̀ fún wa, àwọn aráàlú yóò sọ rere nípa rẹ̀ lẹ́yìn sáà rẹ̀

Buhari and Tinubu

Oríṣun àwòrán, @ShettimaDogo

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe oun yoo tẹsiwaju lati maa ṣawari epo rọbi ni Naijiria ti awọn araalu ba dibo yan oun gẹgẹ bii Aarẹ lọdun 2023.

Tinubu lo sọ ọrọ naa lasiko ti wọn n ṣi ojuko iwakusa epo bẹntiro Kolmani Integrated Development Project (KIPRO), to wa ni ala ipinlẹ Bauchi ati Gombe.

KIPRO yii ni ibi akọkọ ti ijọba apapọ yoo ti maa wa epo rọbi ni Ariwa Naijiria fun igba akọkọ.

A oo tẹsiwaju lati maa wa epo lawọn ipinlẹ mii

Tinubu sọ pe oun yoo tẹsiwaju lori ipinlẹ ti Aarẹ Buhari ti fi lọlẹ, oun yoo si ṣawari epo rọbi lawọn ipinlẹ mii bii Sokoto, Anambra, ati Borno.

O ni “Akitiyan wa lati wa epo lawọn ibomii ni Naijiria ti n so eso rere.

Aṣeyọri yii n tumọ si ilọsiwaju eto ọrọ aje wa, eyii ti yoo ṣe ọpọ araalu lanfaani.”

“Mo fẹ gboriyin fun Aarẹ Buhari ati ajọ NNPC fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.”

 “A oo tẹsiwaju lati ṣawari epo rọbi ni Borno, Sokoto, Bida, Anambra atawọn ibomiran.”

Tinubu tun sọ siwaju sii pe ti oun ba de ipo Aarẹ, oun yoo ṣe afikun adagun Lake Chad fun anfaani gbogbo mutumuwa lọna ati le gbogun ti ebi ati igbesumọmi.”

Awọn eeyan yoo sọ ire nipa Buhari lẹyin saa rẹ

Gomina ipinlẹ Eko nigba kan ri naa tun sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo sọrọ rere nipa Aarẹ Buhari to a pari saa rẹ tan. O ni “Ko ni ṣe nipa ohun ti awọn eeyan ba n sọ lori ayelujara, awọn eeyan yoo sọ ire nipa rẹ ti o ba pari saa rẹ tan nitori o jẹ ọkan lara awọn ajagunfẹyinti to doola Naijiria  kuro ninu iyọnu to wa.”

“Ebi le maa pa wa amọ a ko fẹ maa pa ara wa… o ti ṣi ọna oriire silẹ fun wa.”