Timothy Adegoke yóò wọ ilẹ̀ sùn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, bí ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ rèé

Aworan eto isinku Adegoke

Oríṣun àwòrán, Tunmise Adegoke

Mọlẹbi Timothey Adegoke, akẹkọọ fasiti ti wọn fura si pe awọn kan ṣekupa ni ile itura Ile Ife, ti kede eto isinku rẹ.

Lọjọ Karun un oṣu Kẹwaa ọdun to kọja ni finfinfin nipa iku Timothy Adegoke bẹrẹ si ni jẹ yọ.

Nigba ti wọn yoo fi ri oku rẹ ti ọlọpaa yoo si fi ṣe iwadii, ọrọ naa ti gbode kan ti awọn eeyan si ti n beere pe ki wọn ri pe awọn to ṣeku pa foju wina ofin.

Ninu iwe ipe si ayẹyẹ isinku rẹ ti o tẹ BBC lọwọ,Tunmise Adegoke to jẹ mọlẹbi rẹ ni ilu Eruwa ni ijọba ibilẹ Ibarapa East ni wọn yoo sin si.

Ikede isinku rẹ yii n waye lasiko ti ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ eto igbẹjọ pẹlu awọn ti wọn furasi pe wọn mọ nipa iku Timothy.

Bi eto isinku rẹ ba si se n lọ ni BBC Yoo maa mu wa fun yin.

Ibi ọrọ de duro bayii

Ileeṣẹ ọlọpaa ti pada kede pe awọn yoo wọ Rahmon Adedoyin ati awọn eeyan mẹfa mii lọ siwaju adajọ lori ẹsun to ni ṣe pẹlu iku Timothy Adegoke.

Ni ti Adedoyin, ẹsun ti wọn fi kan kii ṣe ti ipaniyan bi kii ṣe pe o gbimọran pọ lati gbe oku Adegoke si inu igbo.

Lori awọn eyan to ku, ọlọpaa sọ pe awọn fi ẹsun mii bi ẹsun ipaniyan, ilẹdiapopọ,yiyi iwe ẹri owo sisan ati awọn ẹsun mii kan wọn.

Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ ọlọpaa ti ṣe sọ ni ṣoki, Adedoyin yoo foju ba ileẹjọ lori ẹsun pe o yi iwe ẹri ti Timothy fi sanwo hotẹẹli.

Bakan naa yoo salaye ọrọ lori pe o tun gbimọran pọ lati yọ fidio CCTV pẹlu erongba lati yi ẹri pada.

Awọn miran ti wọn pe lẹjọ pẹlu Adedoyin ree:

  • Adedeji Adesola ẹni ọdun 23,
  • Magdalene Chiefuna, 24,
  • Adeniyi Aderogba,ẹni ọdun 37,
  • Oluwale Lawrence, ẹni ọdun37,
  • Oyetunde Kazeem, ẹni ọdun 38,
  • Adebayo Kunle, ẹni ọdun 35 ati awọn mii ti wọn ti na papa bora