Taa ni Tanimu Yakubu tí Ààrẹ Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò olùdarí àgbà fún iléèṣẹ́ ètò ìṣúná Naijiria?

Aworan Tanimu Yakubu

Oríṣun àwòrán, Tanimu Yakubufacebook

Laipẹ yi ni Aarẹ Bola Tinubu kede iyansipo Tanimu Yakubu gẹgẹ bii oludari agba ni ọfiisi eto isuna apapọ ilẹ Naijiria.

Lẹyin ti saa Ben Akabueze pari tan nipo naa ni igbesẹ ọun waye .

Gẹgẹbi atẹjade ti Ajuri Ngelale to jẹ oluranlọwọ aarẹ fun eto iroyin fi sita, lo ti jẹyọ pe Tanimu Yakubu ti ṣaaju wa nipo agbani nimọran agba lori ohun to nii se pẹlu eto ọrọ aje laarin ọdun 2007 si 2010 labẹ Aarẹ tẹlẹri nile Naijiria.

O tun jẹ alabojuto agba fun Banki ayanilowo apapọ ilẹ Niajiria laarin ọdun 2003 si 2007.

Tanimu Yakubu tun jẹ kọmiṣọna fun eto inawo, iṣuna, ati aato ọrọ aje ni ipinlẹ Katsina laarin ọdun 1999 si 2003.

Ilu kurfi, ni ipinlẹ Katsina ni wọn ti bi Tanimu Yakubu ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 1961.

Bakan naa lo kẹkọ gboye pẹlu iwe ẹri lati ile ẹkọ Wagner College, ni ilu New York ati iwe ẹri miran ninu imọ eto ọrọ aje ni ile ẹkọ kan naa.