Tá à bá ti ibodè tó wọ Naijiria, ìyà kò bá jẹ wá lásìkò Coronavirus – Buhari

Buhari

Oríṣun àwòrán, UN

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni ipa to dara ni bi wọn se ti awọn ẹnu ibode to wọ Naijiria pa laarin ọdun kan ti ijọba gbe igbesẹ naa.

Aare Buhari sọ eyi fun Ọbabinrin ilẹ Netherlands lasiko ti wọn ṣe ipade nibi ipade gbogboogbo ajọ United Nations to n lọ lọwọ lorilẹede Amerika.

Oṣu Kẹjọ, ọdun 2019 ni ijọba apapọ paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ibode to wọ Niajiria nitori bi awọn eniyan ṣe n gbe ayederu oogun, ounjẹ ati ohun ijagun wọ orilẹede Naijiria lati awọn ilẹ Afrika to yi Niajiria ka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni Osu Kejila ni aarẹ Buhari paṣẹ ki wọn ṣi ibode naa pada, amọ lẹyin oṣu diẹ ti wọn ṣi ni aarẹ kegbare re pe awọn eniyan n ko ohun ijagun wọ Naijiria lati awọn ibode naa.

Lẹyin naa ni Ile Aṣofin gbe igbesẹ lati ṣi awọn ibode to ku, awọn Ile Aṣofin Agba gbe ẹṣẹ le aṣẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lara ohun ti aarẹ Buhari sọ fun Ọbabinrin Netherlands, Maxima Zoreguieta ni pe, ijọba oun dojukọ ipese awọn iṣẹ akanṣe bii ipese oju ọna to da geere ati awọn ileeṣẹ nla nla, paapaa ọrọ eto ọgbin jẹ oun logun julọ.

Aarẹ ni owo epo bẹntirolu to n lọ soke ko jẹ ki ọrọ aje Naijiria gberu soke si,amọ o fi da Ọbabinrin naa loju wi pe to ba wa si Naijiria bayii yoo ri iyatọ to farahan ju ti ọdun 2017 to wa kẹyin si Naijiria.

Aarẹ Buhari ni igbeṣẹ lati ti ibode naa mu ki awọn eniyan pada si oko, ti wọn si mu eto ọgbin lọkunkun dun, eleyii to mu ki ebi ati iṣẹ dinku lasiko ajakalẹ aarun Coronavirus.

”Ohun to mu mi gbe igbesẹ lati ti ibode naa pa ni lati gba awọn eniyan ni iyanju ki Naijiria ma a jẹ ohun ti wọn n gbin.”

”Awọn eniyan pada si oko, ti a si pese awọn ohun ọgbin bi ”fertilizers”, adagun odo ti wọn nilo lati ṣiṣẹ ọgbin daradara.”

”Ti ko ba si iyẹn, iya ati iṣẹ ko ba pọju bo ṣe lọ lasiko ti aarun Coronavirus ṣe awọn eniyan mọle.”

Ninu ọrọ rẹ, Ọbabinrin naa fi idunnu rẹ han si ipa ti ijọba ko lati bori aarun Coronavirus, to si ṣeleri lati ba Naijiria dowopo lori ọrọ eto ọgbin lati mu idagbasoke ba orilẹede mejeeji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ