‘Sunday Igboho kò yojú sílé ẹjọ́ ní Cotonou, àtìmọ́lé ló ṣì wà’

Sunday Igboho

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ilu Cotonou ni orilẹede Benin Republic fihan pe igbẹjọ ko waye loni nitori Sunday Igboho ko yọju si ileẹjọ.

Akọroyin BBC Yoruba to wa ni Cotonou ni ko si gbẹjọ kankan nitori wọn ko gbe Sunday Igboho wa si ileẹjọ.

Gẹgẹ bi akọroyin wa se wi, awọn eeyan ti n duro lati foju ganni Igboho amọ nigba ti wn ko ri, ni awọn eniyan bẹrẹ si ni kuro ni ileẹjọ.

Ile ẹjọ to yẹ ki igbẹjọ naa ti waye ni wọn n pe ni Paequet, ti iroyin naa si ni ahamọ kan ti wọn n pe ni Brigade De Criminel to wa lagbegbe Berlier, ni wọn fi Sunday Igboho pamọ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iwadii akọroyin naa fihan pe, Sunday Igboho ṣi wa ni agọ ọlọpaa ti wọn n pe ni BRIGADE DE CRIMINEL, nibi ti wọn fi pamọ si.

Lọwọlọwọ awọn eniyan pejọ si agọ ọlọpaa naa lati mọ ipo ti Sunday Igboho wa, amọ ọlọpaa kankan ko i tii bawọn sọrọ.

Agọ ọlọpaa ti Sunday Igboho wa

Amọ wọn ko tii le sọ boya wọn yoo si gbe lọ si ileẹjọ ki ilẹ oni to ṣu.

Bi iroyin naa ba ṣe n lọ ni a o ma a fi to yin leti.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Ọgunjọ, Oṣu Keje, ọdun 2021 ni ẹṣọ agbofinro lati orilẹede Naijiria mu Sunday Igboho ni papakọ ofurufu ni Benin Republic, lẹyin ti ajọ DSS lorilẹede Naijiria kede pe wọn n wa Sunday Igboho fun ẹsun pe o ko ohun ija oloro pamọ si ile rẹ.

Awọn eekan ni ilẹ Yoruba to fi mọ awọn lọbalọba ni wọn ti n ṣepade lori ọrọ naa, ti awọn alakoso Yoruba Nation si n sọ pe awọn yoo sa gbogbo ipa wọn lati ri pe wọn ko gbe Sunday Igboho pade si Naijiria nitori wọn yoo tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ.