Sẹ́nẹ́tọ̀ Ademola Adeleke kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní fásítì l’Amerika

Ademola ati Adedeji Adeleke

Oríṣun àwòrán, Instagram/Ademola Adeleke

Njẹ ẹ ranti sẹnẹtọ onijo? Eyiun ni, Ademola Adeleke to jẹ oludije fun ipo gomina ninu idibo gomina ipinlẹ Osun lọdun 2018.

Sẹnẹtọ Adeleke ti kawe gboye ni fasiti lorilẹede Amerika lopin ọsẹ yii.

Ademola to jẹ aburo baba olorin takasufe, Davido ro dẹdẹ, bẹẹ lo kan dudu nibi ayẹyẹ ikẹkọjade ni fasiti to ti gboye l’Amerika.

Sẹnẹtọ onijo ko ṣai fi idunnu rẹ han loju opo Instagram rẹ.

Oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun lọsun 2018 kọọ soju opo Instagram rẹ pe Ọlọrun dara ni gbogbo igba.

Ọrẹ, ojulumọ ati ẹbi to fi mọ ẹgbọn Sẹnẹtọ onijo, Adedeji Adeleke ati ọmọkunrin rẹ, BRed lo wa nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade naa lorilẹede Amerika.

Ẹwẹ, idile atawọn ọrẹ fi ẹsẹ ra ijo lati ba Ọgbẹni Ademola yọ lori aṣeyọri rẹ.

Koda, ẹgbẹ rẹ Adedeji naa ko gbẹyin, bakan naa ni Ademola fun ra n mi lẹgbẹ.