Rélùwéè yà kúrò lójú ìrìn, orí kò arìnrìnàjò 148, òṣìṣẹ́ NRC ọgbọ̀n yọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, @NigerianTribune

Ajọ to n mojuto eto irinna ojurin ni Naijiria, NRC, ti kede pe irinajo yoo da duro ni oju ọna irin Warri si Itakpe, lẹyin ti reluwee ya kuro loju rin lana.

Ikede naa jẹyọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ NRC ni Warri, Sanni Abdulganiyu, fi lede lana, o ni isẹlẹ naa waye ni ọjọ Aiku, ọjọ kejilelogun ni dede ago mejila abọ.

AbdulGaniyu ni Reluwee to rin irinajo lati Warri lọ si Itakpe lo ya kuro loju irin ninu igbo kan nipinlẹ Kogi, to si mu ibẹru boju ijinigbe ba awọn arinrin ajo.

Aworan

Oríṣun àwòrán, @NigerianTribune

Arinrinajo mejidinlaadọjọ ati awọn osisẹ ọgbọn lo wa ninu reluwee to ya lójú opo rẹ – NRC

“Inu wa dun pe a ko gbọ ibi si ẹni kankan to ba wa rin irinajo naa.

Kete ti a gbọ si isẹlẹ naa, ni a ni ki awọn ẹsọ alaabo lọ darapọ mọ awọn arinrinajo wa lẹsẹkẹsẹ pẹlu iranlọwọ alaga ijọba ibilẹ agbegbe naa.”

Gẹgẹ bo ṣe sọ, arinrinajo mejidinlaadọjọ ati awọn osisẹ ọgbọn lo wa ninu reluwee naa.

O ni awọn kọkọ dola ẹmi wọn, ti wọn si tun pese bi awọn arinrin ajo naa yoo ṣe de si ibi ti wọn lọ.

“Nnkan to fa idi reluwee fi ya kuro loju irin ni a ko le ti sọ bayi sugbọn a ko ni anfani lati tẹsiwaju pẹlu irin ajo fun igba diẹ.

Bo ba ṣe n lọ, a fi to awọn araalu leti, ti a si bẹrẹ isẹ pada laipẹ.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, @NigerianTribune