‘Pásítọ̀ ìjọ t’ọ́lọ́pàá ti kó èèyàn 77 l’Ondo sọ pé ọmọ mi kò gbọdọ̀ ṣèdánwò WAEC ni mo ṣe pariwo síta’

Aworan Pasitọ ijọ Ondo Church, Aworan awọn ọmọ ijọ ti wọn ko si ọdọ ọlọpaa ati aworan arabinrin to pariwo wọn sita

Oríṣun àwòrán, screenshot

Arabinrin to pariwo sita nipa ijọ The Whole Bible Church to wa lagbegbe Valentino nilu Ondo nibi ti ọlọpaa ti ko ọmọ ijọ mẹtadinlọgọrin lọjọ Ẹti, Arabinrin Elizabeth Ruben ti sọ ohun to ṣẹlẹ ti oun fi pariwo ijọ naa sita.

Ninu ifọrọwerọ pẹlawọn akọroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo nilu Akurẹ, arabinrin Ruben ni ọkan lara awọn ọmọ oun to yẹ ko joko ṣe idanwo oniwe mẹwaa WAEC to n lọ lọwọ bayii jẹ ọkan lara awọn ọmọ ijọ naa.

O ni ọmọ oun naa kọ lati joko ṣe idanwo iṣiro ni WAEC to n lọ lọwọ nitori aṣẹ ti pasitọ ijọ naa pa fun un loun fi lọ fi ẹjọ sun awọn aọlọpaa.

Arabinrin Ruben ṣalaye pe Iwaasu ti ijọ naa n wa tako ọrọ Ọlọrun, pe ẹkọ ko dara, pe ki wọn fi iṣẹ gbogbo ti wọn ba n ṣe silẹ, bẹẹ ni oun si n tẹẹ mọ awọn ọmọ oun leti pe ki wọn fi agbo ijọ naa silẹ ṣugbọ ti wọn ko gbọ.

“Akọbi mi ọmọ mi ọkunrin yẹ ko ṣe idanwo WAEC ṣugbọn wọn ni ko gbọdọ lọ ṣe idanwo iṣiro, (Mathematics). Wọn ni pe ohun Ọlọrun sọ pe ko gbọdọ lọ ṣe idanwo iṣiro yẹn.

“Mo rọ ọmọ mi titi, mo bẹẹ titi ṣugbọn o kọ, o ni nitoripe wọn ti sọ fun oun pe ‘bayii ni ọỌlọrun wi’.”

Mo kọwe fi ileewe silẹ ni ipele ikẹta (300 level) nitori aṣẹ pasitọ wa- Ọkan lara awọn olujọsin ijọ The Whole Bible Church Ondo

Aworan Priscilla akẹkọọ ileewe giga to fi ileewe silẹ nitori aṣẹ pasitọ ile ijọsin naa

Oríṣun àwòrán, screenshot

Yatọ si Ọmọkunrin arabinrin Ruben, ọdọbinrin ẹni ọdun mejilelogun kan naa wa ninu ijọ naa, lara awọn ti ọlọpaa ko, to wa ni iwe kẹta ileewe giga imọ nipa imọ ẹrọ ilera, Millenium College of Health Technology nilu Akurẹ, Priscilla Ọlọrunyọmi pẹlu ni lati fi ileewe silẹ nitori ile ijọsin yii ati aṣẹ pasitọ ijọ naa ati igbakeji rẹ.

Ọdọbinrin naa ṣalaye fun awọn akọroyin  pe oun ni lati kọwe ranṣẹ si awọn alaṣẹ ileewe oun pe ki wọn yọnda oun fun igba diẹ naa lati lee gbajumọ ileejọsin naa ati igbaradi fun ipadabọ Jesu ti wọn n fọnrere rẹ.

Baba Priscilla

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Baba ọdọbinrin Priscilla, alagba Michael Ọlọrunyọmi pẹlu ṣalaye pe lati oṣu kini ọdun 2022 ni ọmọ oun ti sa fi ile silẹ nitori aṣẹ ti Pasitọ agba ile ijọsin naa, David Anifowoṣe pa fun un.

O ni ọmọ oun gbe igbesẹ lati fi ileewe silẹ lai gba aṣẹ tabi ifọwọsi oun.

Ki ni Ọlọpaa sọ?

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣalaye bi wọn ṣe mu awọn afurasi naa loju opo twitter wọn.

“ A ran awọn ọlọpaa lọ si ile ijọsin naa lati pe pasitọ ijọ naa ffun ifọrọwanilẹnuwo, awọn ọmọ ijọ naa kọlu awọn ọlọpaa, eyi lo mu ki awọn sọlọpaa to lọ o pe fun alekun ọlọpaa ti wọn fi mu awọn pasitọ wọn ati awọn ọmọ ijọ to kọlu ọlọpaa nibẹ.

“Iwadi wa fihan pe Pasitọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Josiah Oeter Asumosa, to jẹ igbakeji olusọaguntan agba ni ile ijọsin naa lo sọ fun awọn ọmọ ijọ naa pe Jesu yoo pada de ni oṣu kẹrin ọdun 2022, ki o to tun yii pada lati sọ pe o ti di oṣu kẹsan an ọdun 2022, ti o si sọ fun awọn ọdọ inu ijọ naa lati maṣe gbọran si awọn obi wọn lẹnu mọ, ati pe awọn obi wọn ninu oluwa nikan ni ki wọn maa gbọ ọr si lẹnu.

aworan ile iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, screenshot/twitter

“O tun ni ki awọn akẹkọọ  laarin wọn o dẹkun ileewe nitori opin aye ti de tan.

“Baba kan ti ọmọ rẹ wa laarin wọn ṣalaye pe wọn ko jẹ ki oun ri ọmọ oun lati igba to ti n lọ si ile ijọsin naa, bẹẹni awọn ọmọ ijọ naa maa n kọlu ẹnikẹni to ba gbiyanju lati wọ ile ijọsin naa”

Nigba to n ṣalaye bi wọn ṣe mu awọn eeyan naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, SP Olufunmilayọ Ọdunlami sọ pe pasitọ ijọ naa ati igbakeji rẹ yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ fun ẹsun ifipagbenipamọ, kiko awọn eeyan jọ pọ lọna ti ko bofin mu ati fifi ẹta mu awọn eeyan , ati titipasẹ bẹ fi wọn pamọ si abẹ iṣakoso wọn labẹ itanjẹ ẹsin.

O ni ninuawọn eeyan mẹtadinlọgọrin ti wọn mu nibẹ, mẹrindinlọgbọn (26) lo jẹ ọmọde, mẹjọ (8) jẹ ọdọ wẹẹrẹ, mẹtalelogoji si jẹ agbalagba.