Pásítọ̀ bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó fún ìyàwó ọ̀gá akọrin lóyún àti ìjínigbé àwọn ọmọdé

Aworan Kayode Egbetokun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/Facebook

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti mu pasitọ ati oludasilẹ ijọ Christ High Commission to wa ni Araromi-Ugbesia, Omuo-Oke-Ekiti, Noah Abraham lori ẹsun ijinigbe awọn ọmọkekere atawọn eeyan mii.

Ileeṣẹ ọlọpaa mu pasitọ naa pẹlu ibaṣepọ ajọ NAPTIP to n gbogun ti iwa fifi eeyan ṣe kata-kara.

Awọn ọlọpaa mu ọkunrin yii lẹyin tawọn ọmọ ijọ rẹ kan ṣe ifẹhonuhan lọ si agọ ọlọpaa lori ẹsun ijinigbe ati fifun iyawo ọga akọrin loyun.

Ti ẹ o ba gbagbe, ọlọpaa ti mu pasitọ Abraham tẹlẹ ri lori ẹsun pe o gba N310,000 lọwọ awọn ọmọ ijọ rẹ gẹgẹ bi owo iwe irinna si ọrun.

Ohun ti a gbọ nipa pasitọ Abraham bayii ni pe o ti loogun fawọn ọmọde to wa ni akata rẹ o si ti kọ ẹyin wọn sawọn obi wọn.

Nigba tawọn ọmọ ijọ rẹ n sọrọ nibi ifẹhonuhan ti sẹ lọ si agọ ọlọpaa, awọn ọmọ ijọ to fi mọ iyawo pasitọ yii gan an rọ ijọba lati yọ awọn ọmọde atawọn eeyan mii kuro lahamọ pasitọ yii.

Ọkan lara awọn olufẹhonuhan naa ṣalaye pe niṣe ni pasitọ Abraham fi tipa tipa mu ọpọ awọn ọmọde to wa lakata rẹ kuro nile ẹkọ.

O ni bakan naa ni pasitọ yii sọ fun ọkunrin kan ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn to niṣẹ to dara lọwọ to si n fi mọto ṣesẹ rin pe ki o kọwe fipo silẹ ki o si wa si waa maa gbe ni ṣọọṣi oun fun idi pataki kan.

Ọgbẹni Dare Ikuenayo to jẹ ọga akọrin naa fidi rẹ mulẹ pe pasitọ fun iyawo to ti bi ọmọ mẹta foun loyun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, DSP Sunday Abutu ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ọrọ naa.