Oyetola yan akọ̀wé àgbà 30, Adeleke fárígá pé kó jọ ọ́ rárá!

Gba ìwé iṣẹ̀, kí n sì yọyin nípò lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀! – Adeleke

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ti kede pe oun ti buwọlu iyansipo awọn osisẹ ijọba toto ọgbọn niye gẹgẹ akọwe agba fun awọn ẹka ijọba ni o ku ọjọ mẹta ti yoo fi po silẹ gẹgẹ gomina ipinlẹ naa.

Orukọ awọn akọwe ọhun lo wa ni atẹjade ti akọwe agba fun ijọba ipinlẹ Osun, Dokita Festus Oyebade buwọlu fun awọn akọroyin lana.

Oyetola lo lulẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo Gomina to waye ninu oṣu keje, ti Ademola Adeleke lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP si gbe igba aroke.

Sugbọn kete ti ijọba ipinlẹ gbe ikede naa jade ni Gomina tuntun ti ilu dibo yan, Ademole Adeleke fesi pada ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed bu wọlu to si tako igbesẹ naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

O rọ awọn akọwe agba tuntun lati yago ninu igbingba iwe isẹ lati ọwọ ijọba to n ko gba wọle nitori oun yoo gba isẹ lọwọ wọn kete ti oun ba ti bura gun oun gẹgẹ bii gomina.

“A sọ fun awọn araalu bayi pe ẹnikẹni to ba gba iwe isẹ lọwọ gomina Oyetola ko ma reti pe ijọba tuntun yoo gba isẹ lọwọ wọn kete ti wọn ba ti buru fun Gomina tuntun.

“Bakan an, ẹnikẹni to ba fẹ ba Gomina tuntun sisẹ ko rii pe oun yago lati kopa ninu igbesẹ Gomina Oyetola nitori ifa ni, ifa si maa n pa ni.

“Kete ti a ba ti di ori ipo lọjọ kejidinlọgbọn ni a o pa gbogbo asise Gomina tẹlẹ rẹ, ti a o si ṣe atunṣe sii.”