Ọwọ́ tani ìwé ẹ̀rí Adeleke wà? Báyìí ni ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ láàrin Adeleke àti Oyetola ní Tribunal

Ademola Adeleke ati Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Others

Ajọ eleto idibo, INEC, ti sọ pe awọn iwe ẹri gomina tuntun ti wọn dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ko si lọwọ oun mọ.

Alaga ajọ naa nipinlẹ Osun, Ọmọwe Mutiu Agboke, sọ nile ẹjọ to n gbọ ẹsun awuyewuye to waye lẹyin idibo gomina ipinlẹ naa, lọjọ Iṣẹgun pe oun ko ni Form CF 001 ti Adeleke lo lọdun 2018 lọwọ mọ.

Ọsẹ to kọja ni ile ẹjọ naa paṣẹ fun INEC, pe ko mu fọọmu naa wa sile ẹjọ, lẹyin ti olupẹjọ, Gomina Gboyega Oyetola bẹ ile ẹjọ lati ṣe bẹẹ.

Oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ni Gomina Oyetola ati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, fi iwe ẹsun naa ranṣẹ sile ẹjọ.

Form CF 001 ni fọọmu ti oludije fi forukọ silẹ lati dije, ati awọn iwe ẹri ti Adeleke fun INEC lọdun 2018.

Oun to ṣẹlẹ nile ẹjọ Tribunal lọjọ Iṣẹgun

Nibi igbẹjọ eto idibo naa to waye nilu Osogbo, ni agbẹjọro olupẹjọ, Akin Olujimi (SAN) ti ran ile ẹjọ leti aṣẹ to pa fun ajọ INEC, lati ko awọn iwe ẹri Ademola Adeleke wa.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kọkanla ni ile ẹjọ pa aṣẹ naa fun alaga ajọ ọhun.

Olujimi ni ẹlẹrii keji ti oun mu wa sile ẹjọ ko nii sọ ohunkohun, titi INEC yoo fi fi awọn iwe naa han.

O ni awọn ẹri ẹnu onitọhun nii ṣe pẹlu awọn iwe naa.

Ẹni to ṣoju alaga INEC, Ọgbẹni Sheu Mohammed, to tun jẹ igbakeji oludari idibo ati amojuto awọn ẹgbẹ osẹlu ninu ajọ naa, sọ pe Form CF 001 Adeleke ko si lọwọ INEC ti ipinlẹ Osun.

Ọgbẹni Mohammed sọ pe lẹyin eto idibo ọdun 2018, ni awọn ti ko awọn iwe naa lọ si olu ileeṣẹ INEC niluu Abuja.

O ni ẹ̀dà awọn iwe naa ni awọn ni lọwọ nipinlẹ Osun.

“Ẹgbẹ oṣelu lo ko Form CF 001 lọ si olu ileeṣẹ INEC, ẹ̀dà rẹ nikan si ni wọn fun wa, fun akọsilẹ ti wa.”

Ṣugbọn ọrọ to sọ yii ko tẹ agbẹjọro Gomina Oyetola lọrun, eyi to mu ko rọ ile ẹjọ lati paṣẹ fun Alaga INEC nipinlẹ Osun, Ọmọwe Mutiu Agboke, lati kọwe si olu ileeṣẹ INEC fun awọn iwe naa.

Amọ ninu esi to fun, agbẹjọro fun ajọ INEC, Paul Ananaba sọ pe alaga naa ko ni agbara tabi ẹtọ lati beere fun awọn iwe ẹri naa.

Bakan naa ni agbẹjọro fun Adeleke, Onyechi Ikpeazu (SAN), sọ pe ni wọn igba ti awọn olupẹjọ ni awọn iwe ti wọn n beere fun lọwọ wọn, ohunkohun ko gbọdọ si wọn lọwọ lati pe ẹlẹri wọn jade.

Kini ẹlẹri sọ fun ile ẹjọ?

Ẹlẹri keji ti igun Gomina Oyetola mu wa sile ẹjọ, Rasak Adeosun, sọ fun ile ẹjọ pe awọn magomago kan waye lasiko idibo.

Adeosun to jẹ aṣoju olupẹjọ ni ijọba ibilẹ Olorunda lasiko idibo gomina to waye ni oṣu Keje, sọ pe wọn ko lo ẹrọ to n sẹ ayẹwo orukọ oludibo, BVAS, ni ibudo idibo 749 to wa ni ijọba ibilẹ mẹwaa.

Ọgbẹni Adeosun to tun jẹ oluranlọwọ pataki fun Gomina Oyetola, ni awọn aṣoju sọ fun oun pe iye eeyan to dibo pọju awọn to forukọ silẹ lọ.

Lẹyin gbogbo atotonu awọn agbẹjọro, adajọ ile ẹjọ naa, Onidajọ Tertsea Kume, ti sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2022.