Ọwọ́ Sọ́jà tẹ 100 afurasí jàńdùkú tó fẹ́ da ìbò abẹ́nú PDP rú l‘Ekiti

Awọn afurasi janduku ati ohun ija oloro ti Sọja mu

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka Facebook

Bi eto idibo abẹnu ẹgbẹ oselu PDP se n waye nipinlẹ Ekiti loni, lati yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ oselu naa ninu ibo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ naa losu Kẹfa ọdun 2022, gbẹdẹdẹ kan gbina nidaji oni ọjọru.

Idi ni pe ko din ni ọgọrun afurasi janduku tọwọ awọn ologun ti tẹ nipinlẹ Ekiti ni igbaradi fun idibo ati yan oludije gomina fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹbi bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu se fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba, ọwọ awọn ologun tẹ awọn tọọgi naa ni ikorita Ita awurẹ si Ẹfọn Alaye ni ipinlẹ naa.

Deede aago mẹta idaji oni si ni ọwọ sinku awọn janduku naa segi.

Gẹgẹ bii ileeṣẹ ọlọpaa ṣe sọ wọn ti ko awọn afurasi janduku naa lọ si olu ileesẹ ọwọ awọn ologun to wa nilu Akurẹ.

Awọn afurasi janduku ti Sọja mu

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka

Bakan naa ni iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ lati olu ileeṣẹ ọwọ ọmọ ogun nilu Akurẹ pe ifọrọwanilẹnuwo awọn afurasi naa ti bẹrẹ ati pe abajade iwadii wọn yoo jade laipẹ.

Kaadi idamọ awọn osisẹ alakoso gareji n‘Ibadan wa lara awọn afurasi janduku:

Wayio o, ninu iwadii BBC siwaju lati mọ irufẹ eeyan ti awọn afurasi naa jẹ ati ibi ti wọn ti wa, a gbọ pe ilu Ibadan ni awọn janduku naa ti n bọ wa silu Ekiti, ti wọn si ko awọn ohun ija oloro lọwọ.

Lara awọn ohun ija oloro ti awọn ologun ka mọ wọn lọwọ ni ada pana, ibọn ilewọ, ibọn sakabula, igbo mimu ati oogun abnu gọngọ.

Bakan naa ni wọn se afihan kaadi kan to jẹ ti ọmọ ẹgbẹ to n se akoso gareji ọkọ nilu Ibadan eyi ti Alhaji Mukaila Lamidi ti ọpọ eeyan mọ si Auxillary n dari rẹ.

Se ni wọn da awọn afurasi janduku naa joko sori ilẹ, ti wọn si ti gba asọ lara wọn.

Ami idamọ ọmọ ẹgbẹ alakoso gareji labẹ Auxillary

Oríṣun àwòrán, Screen Shot