Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó gé orí, ọwọ́, ọkàn àti ẹsẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ OAU

Omolola Odutola

Oríṣun àwòrán, Omolola Odutola

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ oun ti tẹ ọkunrin meji, Akeem Usman ati Niyi Ifadowo lori ẹsun pe wọn ṣekupa akẹkọọ fasiti OAU kan, Quadri Salami, lati fi joogun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Omolola Odutola lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Odutọla sọ pe baba oloogbe naa ti kọkọ lọ fi ọrọ naa sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Kemta, niluu Abeokuta pe ọmọ oun sọnu, ati pe gbogbo igbiyanju lati ṣawari rẹ lo ja si pabo.

O fi kun pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa funra rẹ, pẹlunawọn ọmọ ẹyin rẹ foju ri ibi ti awọn afurasi naa sin ẹYa ara olooge ọhun si.

“Kọmiṣọna tẹle awọn oṣiṣẹ rẹ lọ sibi ti wọn sin oku oloogbe naa si lati wu oku ọhun to ti n jẹra jade lẹyin ti a ṣawari Usman ti ẹrọ ilewọ oloogbe ọhun wa lọwọ rẹ.

“O darukọ Ifadowo pe awọn mejeji ni wọn jọjọ wu iwa ọdaran naa nipa rirẹ ọrun oloogbe naa, ti wọn si ge ẹya ara rẹ lati fi joogun.

“Ifadowo gbe ori oku naa ati ọwọ rẹ memeji lọ, o san 100,000 naira sinu apo Usman gẹgẹ owo ti wọn pa lẹyin ti wọn ta ẹya ara oloogbe ọhun.

“Lẹyin naa ni awọn afurasi tẹsiwaju lati maa ta ẹya ara oloogbe gẹgẹ bi awọn oni gbajuẹ ori ayelujara ṣe n bere rẹ.

Odutola sọ siwaju si pe wọn sin ọkan ati ẹsẹ oloogbe naa mejeji pẹlu ara rẹ mii sinu igba fun oogun.

Agbẹnusọ ọlọpaa tun ni wọn jẹwọ pe awọn ni ori eeyan mẹrin mii ti wọn ko pamọ ati fi ṣoogun.

Wayi o, o ni awọn afurasi ọhun ti wa lakata ọlọpaa ni ọọfsi ileeṣẹ naa to wa ni Eleweran, niluu Abeokuta bayii, iwadii si ti n lọ lọwọ.

O pari ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ni sinmi titi ti yoo fi fọ ipinlẹ naa mọ lọwọ awọn ọdaran.