
Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ikọ akọṣẹmọṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ti wọn fura si pe o lọwọ si iku DPO ọlọpaa, Bako Angbashim, ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pa ni ipinlẹ Rivers.
Nigba to n fidi aṣeyọri naa mulẹ ninu atẹjade kan, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Bayelsa, Butswat Asinim sọ pe ẹni ọdun mẹtalelogoji ni afurasi naa, Onyekachi Ikowa.
Asinim ni igbagbọ wa pe Ikowa ni igbakeji ọkunrin kan ti wọ n pe ni 2Baba, to jẹ olori ẹgbẹ okunkun Icelanders to ge ori ati nnkan ọmọkunrin DPO naa.
Iroyin ni afurasi naa ti kọkọ salọ si ilu Sagamu, nipinlẹ Ogun, amọ o pada lọ silu Yenagoa nibi ti ọwọ ofin ti ba a lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii.
Atẹjade naa ni “Awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Bayelsa ti mu ọkan lara awọn to ṣekupa oloogbe SP Bako Angbashim, to jẹ DPO Ahoada, nipinlẹ Rivers.”
“Afurasi naa, Onyekachi, to jẹ ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji ni igbakeji 2Baba to jẹ olori ẹgbẹ okunkun Iceland….”
“Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa, CP Fransis Iduh ti ke si awọn agbofinro lati ṣawari awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn ṣi n farapamọ nipinlẹ Bayelsa.”
“O fi kun pe ipinlẹ Baylesa ko ni jẹ ibuba awọn ọdaran labẹ iṣakoso oun.”
Ẹwẹ,awọn ọlọpaa Bayelsa ti fa afurasi ọhun le ileeṣẹ ọlọpaa Rivers ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti ṣekupoa ọlọpaa ọhun lọwọ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 yii ni awọn mọ ẹgbẹ okunkun Iceland naa, ti 2Baba n dari wọn ṣekupa DPO naa, ti wọn si ge ori ati nnkan ọmọkunrin rẹ, ti wọn tun ya fidio awọ ẹya ara rẹ ọhun, eyii ti wọn fi lede lori ayelujara.