Osun 2022: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí ọ̀daràn 18

Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ní ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn méjìdínlógún káàkiri ìpínlẹ̀ náà nígbà tí àwọn ṣe àbẹ̀wò sí gbogbo àyè tó ṣe kókó.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe ti  bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ akin lórí bí ètò ìdìbò tó ń lọ́nà ní ìpínlẹ̀ náà ṣe máa kẹ́sẹ járí.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Yemisi Opalola lo fi ọ̀rọ̀ yìí léde nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejì, oṣù Keje, ọdún 2022.

Opalola ní àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn náà ni àwọn ti ń fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lọ́wọ́ tí àwọn sì máa gbé ìgbésẹ̀ tó nípọn lórí ọ̀rọ̀ ní kété tí ìwádìí àwọn bá ti parí.

Ó wá rọ àwọn ènìyàn láti so ewé agbéjẹ́ mọ́wọ́ pàápàá bí ètò ìdìbò sípò gómìnà yóò ṣe wáyé ní ìpínlẹ̀ náà láìpẹ́ nítorí àwọn kò ní fi àyè ọ̀daràn bó ṣe wù kó mọ lásìkò èyò ìdìbò.

Bákan náà ló rọ àwọn ará ìlú láti máa ṣe àtìlẹyìn fún àwọn agbófinró nípa fífún wọn ní àwọn ìròyìn nípa àwọn ìwà kòtọ́ tó bá ń lọ ní agbègbè kóówá wọn.

Ó ní èyí yóò mú iṣẹ́ àwọn yá, tí ìpínlẹ̀ Osun sì máa dùn-ún gbé fún tẹrú tọmọ pàápàá jìlọ lásìkò ètò ìdìbò tó ń bọ̀ lọ́nà yìí.

“Bí ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun ṣe ń súnmọ́ etílé, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọn gbogbo àwọn ibi tí àwọn ọ̀daràn máa ń sá sí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́.”

“Àwọn méjìdínlógún la ti nawọ́ gán báyìí tí a sì ti ń fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò.”

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àgùnbánirọ̀, òṣìṣẹ́ INEC tó ń ta káàdì ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Osun

Aworan awọn afurasi meji ati kaadi idibo PVC

Oríṣun àwòrán, screenshot/ Police Osun

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọnagunbanirọ ati afurasi miran ti wọn n ko kaadi awọn oludibo pamọ lati ta fun awọn oloṣelu to fẹ fi ṣe ayederu ibo lasiko idibo to n bọ lọna.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, SP Ọpalọla ṣalaye fun awọn akọroyin ni ilu Oṣogbo lasiko to n fi oju awọn afurasi naa han pe ọwọ tẹ wọn lẹyin ti eeyan kan to forukọ silẹ lati gba kaadi idibo lọdọ ajọ eleto idibo INEC lọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa to wa lagbegbe Oṣu ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2022 pe  oun lọ si ọfiisi ajọ INEC to wa nijọba ibilẹ Atakunmọsa West ti olu ileeṣẹ rẹ wa nilu Oṣu lati lọ gba kaadi idibo oun ṣugbọn oun ko rii gba.

O ni oun beere fun iwe iforukọ silẹ awọn to fẹ gba kaadiu nibẹ nibi ti oun ti wa rii pe agunbanirọ kan ti orukọ rẹ n jẹ, Orji Desmond Nkenna, ti o n sinruulu pẹlu ajọ INEC nijọba ibilẹ naa ti gba kaadi ọhun pẹlu igbimọpọ pẹlu arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Wale Ojo ati Ijimakinwa Ọlaoluwa.

Ninu ọrọ to sọ, agunbanirọ naa ṣalaye pe awọn mejeeji yii lo wa ba oun pe awọn fẹ ki oun ko awọn kaadi idibo kan fun awọn nitoripe awọn rii pe awọn mọlẹbi awọn kan ti wa forukọ silẹ fun kaadi ṣugbọn wọn ko si nitosi.

O ni ọgbẹni Wale Ojo naa, to pe ara rẹ fun oun pe oun ni aṣofin to n ṣoju ẹkun  naa ni oun yoo fun oun lowo gọbọi fun iṣẹ naa ti oun ba lee ko awọn kaadi naa fun oun.

Agunbanirọ naa tun ṣalaye wi pe, igbesẹ naa ko ṣai lọwọ oṣiṣẹ ajọ INEC to wa lẹkun ijọba ibilẹ naa, to pe orukọ rẹ ni arabinrin Makanjuọla Bilahu, ẹni ọdun mejidinlọgọta ati arakunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan ti orukọ rẹ n jẹ Oluwatobi Ọginni.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun ṣalaye pe nikete tawọn ọlọpaa gba ifisun naa ni wọn bẹrẹ iṣẹ, wọn mu agunbanirọ naa, oṣiṣẹ ajọ INEC to jẹ ọga rẹ ati ọgbẹni Ọgini to darukọ lati mọ ohun ti wọn mọ nipa iwa naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ko ṣai tun kede pe afurasi meji ninu wọn, Wale Ojo ati Ijamakinwa Ọlaioluwa ti na papa bora ti awọn ọlọpaa si n wa wọn.