Oríire ló jẹ́ fún Sunday Igboho bí ọwọ́ òfin kò ṣe bàá ní Nàìjíríà – Femi Falana

Sunday Igboho:Orííre lo jẹ fún Sunday igboho bí ọwọ́ òfin kò ṣe bàá ni Nàìjíríà-Femi Falana

Agbẹjọ́rò àgbà fún ètọ́ ọmọniyan ni Nàìjíríà Femi Falana ni igbésẹ̀ ìjọba Nàìjíríà lórí ọ̀rọ̀ Sunday Adeyemo ti ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sunday Igboho kò tọ ìlàna ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ̀nuwò tó ṣe pẹ̀lú ilé iṣẹ́ BBC ni Falalana ti ṣàlàyé pé, kò bá òfin mú láti máa ran àwọn ọ̀tẹ́lẹ̀múyẹ lọ si ilé ará ìlú láàrín oru nítorí pé ẹ fẹ́ múu.

Ọ̀pọ̀ ló ti sọ sáájú pé, ó yẹ kí Sunday Igboho dúró láti lọ fa ara rẹ̀ lé òfin lọ́wọ́ ni kàkà ti ó fi sá lọ sí orílẹ̀-èdè Benin Republic.

Falana fèsì lórí èyí pé, nǹkan tó tọ̀nà gan ni Sunday Igboho ṣe nítorí níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ tí le pa ènìyàn méjì tí wọ̀n ko fí ẹ̀sùn kankan kan, nílé Sunday Igboho, ti wọ́n bá ri Igboho fúra rẹ̀, wọ́n yóò pa ni.

“Bí ó ṣe jàjàbọ́ nínú wàhálà ti wọn kó wá sí ilé rẹ̀, ore-ọ̀fẹ́ ló ní.”

Bákan náà ni Falana bèrè pé nínú òfin, ta ni o ni ẹ̀tọ́ láti mú ènìyàn, tí wọ́n fi àwọn ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan Sunday Igboho kan, gẹ́gẹ́ bí òfin Falana ní ọlọ́paàá lo ni iṣẹ́ náà, sùgbọ́n kílódé tí ìjọba ń lo DSS.

“DSS ko ni agbára kankan lábẹ́ òfin lati lọ mu ènìyàn tó ṣẹ irú ẹ̀sun ẹ̀sẹ̀ ti ìjọba fi kan Sunday Igboho, òfin kílódé tí ìjọba ko bọ̀wọ̀ fún òfin?”.

Falana ni bí o tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tí Sunday Igboho sọ pé òun fún àwọn Fulani ni gbedeke láti fi ilẹ̀ Yorùbá sílẹ̀, òun gẹ́gẹ́ bi ọlọ́dani ko faramọ̀ igbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà gbogbo ẹ̀, o ṣi lẹ́tọ̀ọ́ sí ominira ara rẹ̀ àti ìdájọ́ òdodo.

Lórí ọ̀rọ̀ Nnamdi Kanu

Falana ni ọ̀rọ̀ Nnamdi Kanu yátọ nítorí pé, ó sá kúrò ni Nàìjíríà lásìkò tó n kójú ìgbẹ́jọ́ lọ́wọ́.

Ẹ̀wẹ̀, lábẹ́ àkóso bí ó tí wù kí ó rí gbogbo ìgbésẹ̀ ìjọba gọdọ̀ bá òfin mu, gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ ó ni wọ́n ji Kanu gbé ni orílẹ̀-èdè Kenya ni ti wọ́n sì gbé wá sí Nàìjíríà.

Irú ìwà tí ìjọba Nàìjíríà gùnlé yìí, ìwá ọ̀daràn ni kìí ṣe ìwà tó bá ojúmu tí ó yẹ jí ìjọba máa gùnlé.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ