Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Dókítà, àtàwọn òṣìṣẹ́ wá kọ̀wé fipò sílẹ̀ láti ‘Japa’ lọ sí ìlú Òyìnbó – UCH Ibadan

Aworan

Oríṣun àwòrán, UCH

Adari agba fun ile iwosan ikọṣẹ imọ iṣegun Oyinbo ni fasiti ilẹ Ibadan, UCH, Ọjọgbọn Abiodun Otegbayo ti pe fun igbesẹ lati wa ojutuu si gbogbo idiwọ to n koju igbanisiṣẹ awọn oṣisẹ tuntun si awọn aye to ṣofo nipasẹ ọgọrọ awọn oṣisẹ eto ilera to n rin irinajo lọ si oke okun.

Otegbayo fi ọrọ naa lede l’ọjọ Aje nibi ipade awọn oniroyin ti o waye lati ṣe ami ayẹyẹ ọdun ‘karundinlaadọrin ti wọn ti ṣe idasilẹ ile iwosan UCH, ilu Ibadan.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, o ni gbogbo ọsẹ ni oun n buwọlu o kere tan, ikọwefiposilẹ mẹẹdogun lati ọwọ awọn oṣisẹ ilera nile iwosan naa, paapaa julọ awọn Dokita, Nọọsi, awọn to n ṣe akoso lilo ogun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Otegbayo ni laarin ọdun 2020 si ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa odun 2022, egbẹta oṣisẹ eto ilera lo ti kuro nile iwosan naa, ti ile iwosan naa si n koju idiwo lati gba awọn oṣisẹ tuntun si ẹnu isẹ.

O tẹsiwaju wi pe kaakiri agbaye ni ikọwefiposilẹ ti n waye, ti eleyii si n mu adinku ba iye awọn oṣisẹ ti o yẹ ki o wa lẹnu isẹ nitori aisi itọju ti o peye, aabo ati bẹẹ bẹẹ lọ fun awọn oṣisẹ.

Otegbayo ni ile iwosan UCH ti n sisẹ eto ilera to kun oju osunwọn lorilẹede Naijiria ati ni ẹkun Iwọ-Oorun ilẹ adulawọ, pẹlu alaye wi pe ile iwosan naa yoo tẹsiwaju ninu ojuṣe rẹ gẹgẹ bi atunṣe ṣe n ba awọn ohun elo amayedẹrun ati awọn oṣisẹ.

O gbe oṣuba kare fun awọn oṣisẹ ile iwosan naa fun ifokansin ati ipa ti wọn n sa fun igbega ile iwosan naa ati itọju awon alaisan.