Ọ̀pọ̀ èrò há, àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú daṣẹ́ sílẹ̀ ní pápákọ̀ Muritala Muhammed Eko

Papakọ Muritala Muhammed

Ọpọ awọn ero to fẹ wọ ọkọ ofurufu ní owurọ ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kiini ọdún 2023 ni wọn ko ribi lọ bi awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu Muritala Muhammed ṣe bẹrẹ iyanṣẹlodi.

Ifẹhonuhan nitori ikuna awọn alabojuto ile iṣe Nigerian Aviation Handling Company Plc lati fi kun owo oṣu ni awọn oṣiṣẹ naa fi kọkọ bẹrẹ.

Atẹjade kan ti apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ọkọ ofurufu fi lede ni awọn bẹrẹ iyanṣẹlodi naa nitori idunaadura ti NAHCO ṣe pẹlu awọn alaṣẹ lati fowo kun owo oṣu awọn oṣiṣẹ ko so eso rere.

Igbesẹ ti wa fa idaduro fun awọn ero to fẹ wọ ọkọ ofurufu paapaa awọn to n lọ si ilẹ okeere.

Iroyin ọgọọrọ awọn eniyan lo wa ni awọn ibi ayẹwo awọn ero-irinna ti iyanṣẹlodi yii ti mu ki ọpọlọpọ padanu anfani lati rinrin ajọ lonii.

Iyanṣẹlodi yii kọ ni akọkọ ti awọn ajọ oṣiṣẹ ọkọ ofuurufu Naijiria yoo ṣe

Awọn to n ṣe ifẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Others

 Ni Oṣu Kẹsan-an ọdun 2022,  Ijọba orilẹ-ede Naijiria labẹ aarẹ Muhammadu Buhari gbero lati ṣe ofin ti yoo mu ki awọn oṣiṣẹ ọkọ ofurufu ni orilẹ-ede yii ma daṣẹ silẹ mọ.

Ọkan lara awọn arinrin-ajo to ba awọn akọroyin sọrọ ni ṣadede ni awọn oṣiṣẹ ọkọ ofurufu kede pe awọn awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ti wọn o si ni da awọn arinrin-ajo lohun.

O ni ọkọ ofurufu Qatar ti o yẹ ki oun barin ba silẹ lafẹmọju oni ṣugbọn wọn o jẹ ki awọn wọ inu rẹ ki ọkọ naa to gbera kuro ninu papakọ ofurufu Murtala Muhammed pada.

Awọn arinrin-ajo ro ijọba apapọ lati yanju ohun to n fa idi ti àọn oṣiṣẹ fi n daṣẹ silẹ yii ni kiakia ki irinajo silẹ okeere le tẹsiwaju.