Ọmọ tó rẹwà ni Adaolisa Emmanuella, gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe irun rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, a kò mọ̀ pé ọkùnrin ni – Alábàágbé

Adaolisa Emmanuella

Oríṣun àwòrán, Adaolisa Emmanuella /Facebook

Àwọn alábàágbé tó ń gbé ilé kan náà pẹ̀lú Emmanuel Adaolisa ní kàyéfì ṣì ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣì ń jẹ́ fún àwọn títí di àsìkò yìí nítorí àwọn kò mọ̀ rárá pé ọkùnrin ni nígbà tí wọ́n bi.

Àwọn tó ń lọ ilé ìjọsìn Àgùdà St John tó wà ní Rumuolumeni, Iwofe, Port Harcourts, ìpínlẹ̀ Rivers pẹ̀lú Emmanuella ló ṣàfihàn rẹ̀ pé ẹni tó jẹ́ akọrin obìnrin ní ilé ìjọsìn ni kìí ṣe obìnrin látilẹ̀ ṣùgbọ́n tó pàwọ̀dà.

Ní ilé ìgbókúùsí, nígbà tí wọ́n ń ṣe ìtọ́jú òkú Emmanuella lẹ́yìn tó ní ìjàmbá ọkọ̀ tó sì gbabẹ̀ kú, ló ṣàwárí rẹ̀ pé òkú náà kìí ṣe obìnrin tí wọ́n pèé.

Ọgbà inú ilé tí Adaolisa ń gbé ní Port Harcourt

Oníwàpẹ̀lẹ́ ni Emmanuella, a kò fura rárá pé ọkùnrin tó ń ṣe bíi obìnrin ni – Àwọn ará ilé Adaolisa sọ̀rọ̀

Nígbà tí BBC kàn sí ilé tí Emmanuella ń gbé ní Rumuolumeni, àwọn alábàágbé rẹ̀ ní nínú oṣù Kẹjọ sí oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022 ló kó dé ilé náà tí àwọn sì jọ ń gbé pẹ̀lú àláfíà.

“Ọmọbìnrin tó rẹwà ni Ada, ó ní ìtẹríba nítorí òun ló máa kọ́kọ́ kí i yín tí ẹ bá pàdé ní òwúrọ̀.”

Tammy tó ń gbé iwájú yàrá Emmanuella ní jẹ́jẹ́ ẹ̀ ló máa ń lọ ṣùgbọ́n ó máa ń kópa nínú gbogbo nǹkan tí a bá ń ṣe nínú ilé.

Charles, tó tún jẹ́ alábàágbé rẹ̀ ní àwọn kò fura rárá pé ọkùnrin tó pa ara rẹ̀ dà sí obìnrin ní Emmanuella nítorí àwọn gbàgbọ́ pé kìí ṣe gbogbo obìnrin náà ló máa ń ní ọmú àti ìdí ńlá.

Ó ní gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe irun rẹ̀ dáadáa tàbí kó lo wíìgì, tí yóò ṣe èékánná tí yóò gún régé, tó sì tún máa ń kun àtíkè dada.

“Lọ́pọ̀ ìgbà tá bá ń ṣe ìpàdé nínú ilé ló máa ń wọ ṣòkòtò kékeré wá tí a kò sì ní fura kankan nítorí náà ló ṣe yàwá lẹ́nu nígbà tí òkìkí kàn pé ọkùnrin ni.”

Ó fi kun pé nǹkan tí òun kàn mọ̀ ní pé Emmanuella máa ń paramọ́ gidi gan, pé kìí sa aṣọ rẹ̀ síta bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìta ni maṣíìnì ìránṣọ rẹ̀ wà, inú yàrá kan ló máa ń sa aṣọ rẹ̀ sí.

Ó ní síbẹ̀ àwọn kò fura kankan nítorí àwọn kò rò ó si rárá àmọ́ nísìn-ín ni àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rò ó pé bóyá nítorí náà ni kò ṣe kí ń sa aṣọ síta.

Àwọn ará ilé ń fẹ́ kí àwọn ẹbí wá kó ẹrù rẹ̀ kúrò

Ẹ̀gbẹ́ ilé ni ìjàmbá ọkọ̀ tó gbẹ̀mí Adaolisa ti wáyé

Ibi tí Adaolisa ti ni ìjambá ọkọ̀

Àwọn alábàágbé Adaolisa ní ibi tí ìjàmbá ọkọ̀ tó mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ kò jìnà sílé rárá, bí ilé mélòó kan ni sí òpópónà Easy Vil, èyí tí wọ́n ń gbé.

Mbaah tó jẹ́ alábàágbé rẹ̀ mìíràn ní oníṣẹ́ ọwọ́ kan tó ń ṣiṣẹ́ lórí omi ilé àwọn ló sáré wá pe àwọn pé ará ilé àwọn kan ti ní ìjàmbá ọkọ̀.

Ó ní bí àwọn ṣe dé ibi tí ìjàmbá náà ti wáyé ni àwọn ri tí ẹ̀jẹ̀ ti ń yọ lára rẹ̀, fóònù rẹ̀ ti jábọ́ sí gọ́tà ṣùgbọ́n àwọn yọ síìmù ibẹ̀ láti wá nọ́mbà láti fi pe ẹni tí àwọn bá rí níbẹ̀.

“Nọ́mbà tí a kọ́kọ́ rí lórí fóònù náà ni dókítà kan, nígbà tí a pè é láti sọ fún pé obìnrin tó ni nọ́mbà náà ní ìjàmbá ọkọ̀, ẹni náà sọ wí pé ọkùnrin ni ẹni tó ni nọ́mbà náà tí òun mọ̀, ló bá pa fóònù.”

“A pe ènìyàn méjì mìíràn, èsì kan náà ni àwọn náà fọ̀ jáde pé àwọn kò mọ obìnrin kankan tó ń jẹ́ Adaolisa.”

“Nígbà náà la ronú ilé ìjọsìn tó ń lọ la fi lọ pé àlùfáà ìjọ náà, tí wọ́n sì wá gbe lọ sí ilé ìwòsàn.”

Mbaah fi kun pé nígbà tí wọ́n sọ nílé ìgbókúùsí pé ọkùnrin ni àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ wáronú gbogbo èsì tí àwọn pè lórí fóònù fún àwọn.

Kò sí ẹbí kankan tó wá Adaolisa wá rí

Àwọn ẹrù Adaolisa Emmanuella

Charles ní láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé kò sí ẹbi kankan tó wá Adaolisa wá sílé àwọn láti wá bèèrè rẹ̀.

Ó ní ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó jẹ́ ọkùnrin ló wá sunkún nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé àmọ́ láti ìgbà náà onítọ̀hún kò padà wá mọ́ títí di àsìkò yìí.

“Kò sí ẹnikẹ́ni tó ti wá sí ilé yìí nítorí ẹni tó gbé ilé fun gan ń wá àwọn ẹbí rẹ̀ lórí bí wọ́n ṣe máa kó ẹrù rẹ̀ kúrò nínú ilé.”

Ó nígbà tí àwọn gbọ́ pé àwọn ẹbí rẹ̀ wá sí ilé ìjọsìn láti wá gba òkú rẹ̀ ní mọ́ṣúárì, ẹni tó gbé ilé fún-un wá bàbá rẹ̀ lọ sí ilé ìjọsìn àmọ́ nígbà tó máa fi dé ibẹ̀, bàbá rẹ̀ àti àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì ti kúrò níbẹ̀.

Àwọn ará ilé náà ní Adaolisa máa ń wọ òrùka ìfẹ́ kan tó sì máa ń sọ wí pé òun kò ní pẹ́ ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú àfẹ́sọ́nà òun tó wà ní òkè òkun.”

Bákan náà ni wọ́n fi kun pé Adaolisa ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀ tó máa ń wa wá àmọ́ kò sí èyí tó yọjú nínú wọn láti ìgbà tó ti kú.

Nígbà tí BBC Pidgin kàn sí ilé ìjọsìn ìjọ Àgùdà St John tí Adaolisa ń lọ, wọn ò bá ẹnikẹ́ni níbẹ̀.

Àwòrán ilé ìjọsìn Àgùdà St John

Ẹ̀ṣẹ̀ ni ìbálòpọ̀ akọ sákọ àti abo sábo ní Nàìjíríà

Kí ọkùnrin máa ṣebí obìnrin tàbí kí obìnrin máa ṣe bíi ọkùnrin jẹ́ ohun tí àwọn ènìyàn máa korò ojú sí ní Nàìjíríà.

Ọ̀pọ̀ tilẹ̀ máa ń gbà pé ẹ̀mí àìrí kan tí kò dára ló ń bá ẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́.

Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ máa ń gbé ara wọn pamọ́ nítorí bí wọ́n ṣe máa ń bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n, tí wọ́n sì máa ń gbé ara wọn pamọ́ fún ẹbí àti ọ̀rẹ́.

Bákan náà ni ìgbéyàwó láàárín akọ sí akọ tàbí abo sí abo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó ní ìjìyà lábẹ́ òfin Nàìjíríà, ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá ni ẹni tí wọ́n bá gbámú yóò fi jura.

Àmọ́ òfin Nàìjíríà kò ní kí ọkùnrin tàbí obìnrin má múra bó ṣe wù wọ́n ìbáà ṣe wí pé ọkùnrin fẹ́ máa múra bí obìnrin tàbí obìnrin fẹ́ máa múra bíi ọkùnrin.

Àwọn nǹkan tí a mọ̀ nípa Adolisa Emmanuel

Adaolisa Emmanuella

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ilé ẹ̀kọ́ girama tó jẹ́ ti àwọn ọkùnrin nìkan ìyẹn Metropolitan Secondary School, Onitsha èyí tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Metro ni Adolisa lọ.

Ó kọ́ ẹ̀kọ́ nípa oògùn pípò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Port Harcourt.

Ó jẹ́ ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìjọ Àgùdà gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn nínú ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó ń fi sórí ayélujára rẹ̀.

Bákan náà ló ní ìmọ̀ púpọ̀ orin kíkọ, tó sì mọ àwọn ohun èlò orin bíi gìtá àti violin lò dada.

Àkáǹtì Facebooko méjì ló ní ìkan pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀, Emmuel Nwolisa, ọdún 2021 ló ti fi àwòrán síbẹ̀ kẹ́yìn.

Àkáǹtì kejì ni èyí tó ti ń jẹ́ Emmanuel Adaolisa tó ṣí ní ọdún 2022 nígbà tó paradà di obìnrin.